Adegoke Adewumi
‘‘Ki i ṣe nitori ọrọ ẹsin ni mo fi mu Shettima gẹgẹ bii igbakeji mi, ki i si i ṣe nitori pe n ko ka awọn Onigbagbọ si tabi pe mo ni ete kan lọkan to fara sin, nitori ọgbọn ayo oṣelu ni mo ṣe mu un’’.
Oludije funpo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu, lo sọrọ yii di mimọ lasiko ipade to ṣe pẹlu awọn ẹgbẹ Onigbagbọ (CAN), niluu Abuja l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu yii. O ṣalaye fun wọn pe ati Musulumi ati Onigbagbọ lo ma gbadun ijọba oun.
‘‘Looootọ lo maa rọrun fun mi ti mo ba fẹẹ yan Onigbagbọ gẹgẹ bii igbakeji mi, ṣugbọn ọrọ ko ba bẹẹ lọ. Idi ti mo fi yan Shettima ni pe mo ri awọn ipenija to n poungbẹ fun atunṣe nilẹ wa, Shettima si jẹ ẹni to ni awọn amuyẹ lati dojukọ awọn ipenija yii nitori o ti fi iwa aṣaaju yii han lasiko to n ṣe gomina ipinlẹ Borno.
‘‘Ijọba Onitẹsiwaju ni mo fẹ lati ṣe, idi niyi ti mo fi yan Shettima gẹgẹ bii igbakeji mi. A ni awọn ipenija to fẹ amojuto, ti ko si yẹ ki a fi ti ẹsin ṣe, bi ko ṣe ẹni to kun oju oṣuwọn to le ṣiṣẹ naa.
Siwaju si i, Tinubu ni aarẹ Naijiria ti oun fẹẹ ṣe, ki i ṣe nipa ti ẹsin, bi ko ṣe nipa ofin ilẹ wa.
O waa ṣeleri fun awọn ẹgbẹ Onigbagbọ yii pe ọrọ Musulumi to jẹ oludije funpo aarẹ ati igbakeji ko ni i mu wahala kankan wa fun wọn.
O ni awọn nnkan ribiribi ti oun ṣe lasiko ijọba oun nipinlẹ Eko loun yoo ṣe bi oun ba di aarẹ Naijiria.
O fi ẹmi imoore rẹ han fun ẹgbẹ Onigbagbọ yii fun bi won ṣe pe e lati waa sọ awọn ohun to ni lọkan lati ṣe.
O fi kun un pe Onigbagbọ ni iyawo oun, awọn ọmọ oun paapaa wa ti wọn jẹ Onigbagbọ, ti oun ko si di wọn lọwọ lati ṣe ẹsin to wu wọn ti wọn n ṣe. O ni o jẹ ohun to ba ni lọkan jẹ pe ki awọn kan maa sọ pe oun fẹ tẹ awọn Onigbagbọ ri loun fi mu Musulumi gẹgẹ bii igbakeji oun.
Lara awọn to kọwọọrin pẹlu rẹ ni igbakeji rẹ, Kashim Shettima, iyawo rẹ, Olurẹmi Tinubu, Olori ileegbimọ aṣoju-sofin, Fẹmi Gbajabiamila atawọn mi-in.