Tinubu ṣedaro iku Kaṣamu, o ni ko daa kẹnikẹni sọrọ odi si oku ọrun

Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmed Tinubu, ti ṣedaro iku to pa Oloogbe Buruji Kaṣamu, ọkan ninu awọn oloṣelu nla nilẹ Yoruba wa. Aṣiwaju ni ẹni kan ti i maa i ja fun ohun to ba nigbagbọ ninu ẹ tọkantọkan pẹlu gbogbo agabra to ni ni Kaṣamu. Ati pe bo tilẹ jẹ pe awọn ko si ninu ẹgbẹ oṣelu kan naa, oun fẹran ọgbọn ati ọna oṣelu rẹ, o si daju pe orilẹ-ede yii ti sọ ọkan ninu awọn ọlọpọlọ nidii oṣelu nu. pẹlu iku to pa Ẹṣọ Jinadu yii.

Tinubu ni iku to pa Kaṣamu yii tubọ n fi ye gbogbo eeyan, ati gbogbo ẹni yoowu to ba lagbara laye, pe ko ṣeni kan ti ko ni i lọ sibi to lọ, nitori bẹe, ki i ṣe ohun to dara lati maa sọrọ eebu, tabi ọrọ odi si ẹni to ba ti ku, nitori gbogbo ẹda pata naa ni yoo lọ sọrun. Ọkunrin oloṣelu nla naa ni Kaṣamu ti lọ ni tirẹ, tẹni to ku ni a ko ti i mọ, eyi si ni kaluku ṣe gbọdọ maa huwa rere.

Ijẹta lọjọ Abamẹta, Satide, ni iku deede fa Kaṣamu yọ laarin gbogbo adarihurun, ajakalẹ-arun korona yii si ni iku lo lati mu un ̀lọ. Ana naa ni wọn gbe e gbin bii ebu-iṣu ni Ijẹbu Igbo, nibi ti ero ti tì bii omi, ti ko si sẹni kan to fẹẹ ranti pe korona lo pa a, tabi pe korona to pa a le mu awọn. Ohun ti wọn n sọ ni pe eeyan rere ni Buruji Kaṣamu, awọn si ni igbagbọ pe ọrun rere ni yoo lọ.

 

 

Leave a Reply