Tinubu ati Shettima ni yoo wọle ibo aarẹ lodun 2023- Lawan

Monisọla Saka

Olori ileegbimọ aṣofin ilẹ wa, Ahmad Lawan, ti fọwọ sọya pe ẹgbẹ oṣelu APC, pẹlu awọn oludije dupo aarẹ ninu ẹgbẹ awọn, Aṣiwaju Bọla Tinubu ati Kashim Shettima, ni yoo wọle ibo aarẹ ọdun 2023. Lasiko to n sọrọ nibi apejẹ ti wọn ṣe fawọn agba ati oludamọran ẹgbẹ wọn lolu ileeṣẹ ipolongo ibo wọn niluu Abuja lo ti sọrọ naa.

Lara awọn agba ẹgbẹ ati oludamọran ẹgbẹ wọn yii ni awọn gomina tẹlẹri, awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin, awọn minisita, awọn oloṣelu to ti laami laaka, atawọn to ti figba kan dipo kan tabi ekeji mu nileeṣẹ aarẹ.

Ninu ọrọ ẹ, aarẹ ileegbimọ aṣofin ọhun ti ni ọkan oun balẹ pẹlu Tinubu ati Shettima lori awọn nnkan rere ti wọn ti gbe se nidii oṣelu latẹyin wa.

O ni, “Ko si ani-ani ninu pe ẹgbẹ oṣelu APC ni yoo jawe olubori ninu ibo to n bọ yii pẹlu Bọla Ahmed Tinubu ati Kashim Shettima to jẹ pe eeyan pataki ti wọn ti ṣe aṣeyọri ninu irinajo oṣelu ni wọn”.

Nigba to n ba awọn ti wọn n ṣẹyẹ fun sọrọ, Tinubu ṣapejuwe awọn agba ẹgbẹ naa bii awọn eeyan iyi ti wọn ti ṣiṣẹ fun ẹgbẹ, ti wọn si ti faya ran iṣoro fun idagbasoke ijọba alagbada nilẹ Naijiria.

Leave a Reply