Tinubu di aarẹ Naijiria kẹrindinlogun

Faith Adebọla
Ni ba a ṣe n sọ yii, wọn ti ṣebura wọle fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, o si ti di aarẹ ilẹ Naijiria tuntun.

Nnkan bii aago mẹwaa aabọ owurọ yii, ni wọn Adajọ agba ilẹ wa, Onidaajọ Kayọde Ariwoọla ṣebura fun un, ninu gbagede Eagle Square, l’Abuja nibi ti eto ibura wọle naa ti waye.

Tinubu, to wọ agbada nla funfun kinninwin, pẹlu fila alawọ ewe ti wọn ya ami idanimọ kan to saaba maa n wa lara awọn fila rẹ si, si, ka awọn ẹjẹ ati ibura ti wọn ṣakọọlẹ rẹ sori iwe to wa lọwọ rẹ. Bi Ariwoọla ti n ka awọn ẹjẹ naa jade, ni Tinubu n wi bẹẹ tẹle e.

Lara awọn ọrọ ibura naa ni ẹjẹ ti Tinubu jẹ lati pa ofin orileede yii mọ, lati ja fun iṣọkan ilẹ Naijiria, ati lati daabo bo olugbe ati dukia ilu ati tawọn ọmọ orileede yii.

Lẹyin kika ẹjẹ naa tan lori iduro, o jokoo, o si buwọ lu awọn iwe majẹmu naa. Lẹyin eyi ni wọn ṣebura bakan naa fun igbakeji rẹ, Kaṣhim Shettima, toun naa si buwọ luwee.

Ẹyin eyi ni Aarẹ ana, Muhammadu Buhari fa asia orileede yii tuntun ati iwe ofin orileede yii le Tinubu lọwọ, awọn omoogun tu asia naa, lẹyin ti wọn ti rọ asia to wa lori opo tẹlẹ walẹ, wọn ta asia tuntun naa soke, o fẹ lẹlẹ, lati fi ami han pe ijọba kan ti tẹnu bọpo, omi-in si ti bọ sori aleefa bayii.

Lẹyin eyi ni Tinubu ko sinu ọkọ ọlọpọn tawọn ologun, awọn ṣọja bii mẹta wa lẹyin rẹ, wọn si gbe e yipo gbogbo gbagede naa, o n juwọ sawọn eeyan, o n fi idunnu rẹ han, bẹẹ lawọn eeyan n rẹrin-in si i, ti wọn si n ki i kuu oriire.  


Leave a Reply