Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, ni awọn agba ẹgbẹ oṣelu APC, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ṣepade pẹlu aṣaaju ẹgbẹ oṣelu ọhun, Asiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ati Oloye Bisi Akande, niluu Abuja, wọn fontẹ lu Fagbemi gẹgẹ bii alaga tuntun, wọn si ti bẹrẹ ipẹtu saawọ pẹlu igun ikeji ti inu n bi ninu ẹgbẹ.
Eyi lo waa bu omi tutu si ọkan ẹgbẹ oṣelu alatako kan gboogi nipinlẹ Kwara, PDP latari pe adari ẹgbẹ naa, Bukọla Saraki, ti n ṣepade pẹlu awọn kan ti inu n bi lẹgbẹ APC, pẹlu ẹrongba lati darapọ mọ PDP nipinlẹ naa. Ṣugbọn ti ipẹtu-saawọ ti Tinubu n ṣe yii ba seso rere, a jẹ pe ireti ẹgbẹ oṣelu PDP ni Kwara ja si pabo ni, ti ẹgbẹ APC yoo si tun fẹsẹ mulẹ si i.
Tẹ o ba gbagbe, Sunday Fagbemi ti ẹgbẹ ṣẹṣẹ dibo yan gẹgẹ bii alaga tuntun nipinlẹ naa lo ti pinnu lati yanju aawọ pẹlu awọn ti inu n bi ninu ẹgbẹ, to si ti lọọ ṣabẹwo si Tinubu niluu Abuja ati Oloye Bisi Akande ni Ila Ọrangun.