Tinubu ko ẹri rẹpẹtẹ siwaju ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun idibo

Monisọla Saka

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrin, oṣu Keje, ọdun yii, ni Aarẹ orilẹ-ede yii, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, bẹrẹ ijẹjọ rẹ niwaju awọn igbimọ adajọ to n ri si awuyewuye to tibi eto idibo aarẹ oṣu Keji, ọdun yii jade.

Ninu ẹsun ti oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Alaaji Atiku Abubakar, pe ta ko Tinubu ati ẹgbẹ oṣelu APC, ni Aarẹ ti ko awọn ẹri wa. Lara rẹ ni awọn iwe-ẹri atawọn iwe mi-in to fidi ẹ mulẹ pe o lọ si Chicago State University.

Olori awọn agbẹjọro Tinubu, Oloye Wọle Ọlanipẹkun, lo ko awọn iwe yii siwaju ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun idibo aarẹ, Presidential Election Petition Court (PEPC). Bakan naa ni wọn tun mu lẹta kan kalẹ, lẹta ọdun 2007 yii, ni wọn lo wa lati ileeṣẹ ilẹ Amẹrika to wa ni Naijiria, (American Embassy), eyi ti wọn lo lati fi wẹ Tinubu mọ kuro ninu oniruuru ẹsun ọdaran lorilẹ-ede Amẹrika.

Iwe tawọn ileeṣẹ ọlọpaa Ilẹ Naijiria kọ sileeṣẹ aṣoju ilẹ Amẹrika ti wọn wa ni Naijiria naa wa lara eyi ti lọọya ẹ ko siwaju awọn adajọ.

Ninu awọn iwe ẹri to ti ileewe giga Chicago State University wa, ni wọn ti ri sabukeeti mejila ọtọọtọ. Lati ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun yii, si ni wọn ni amofin agba nileewe giga ọhun, Jamar C. Orr, ti buwọ lu u.

Awọn ikọ agbẹjọro Tinubu tun ko awọn oriṣii iwe mẹfa kan kalẹ to ṣafihan lilọ bibọ, fisa gbigba ati eto irinna Tinubu lọ silẹ Amẹrika, laarin ọdun 2011 si 2021, atawọn ẹri mi-in ti yoo fi rojọ jare ẹsun ti Atiku fi kan an.

Leave a Reply