Tinubu ko yọju sibi ipade awọn agbaagba ẹgbẹ APC l’Abuja

Ọrẹoluwa Adedeji

Ko ti i sẹni to mọ idi pataki ti Aṣiwaju Bọla Tinubu ti wọn dibo yan lati dije dupo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC lọdun to n bọ ko ṣe si nibi ipade awọn agbaagba atawọn alẹnulọrọ ẹgbẹ APC to waye niluu Abuja lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii.

Aarẹ Buhari lo ṣepade pataki pẹlu awọn agbaagba ẹgbẹ APC, ninu eyi to yẹ ki Tinubu wa nibi ijokoo ipade yii gẹgẹ bii ọkan ninu awọn agbaagba ẹgbẹ naa, ṣugbọn ọkunrin naa ko yọju sibẹ, bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe pe o ti kuro ni orileede Naijiria.

Bakan naa ni awọn gomina lati ilẹ Yoruba ko yọju sibẹ, bo tilẹ jẹ pe awọn ojugba wọn ninu ẹgbẹ APC lati awọn ipinlẹ l’Oke Ọya wa nibẹ.

Ko sẹni to mọ ohun ti ipade naa da le lori, ṣugbọn alaga APC nigba kan, Audu Ogbeh, Olori awọn aṣofin agba, Ahmed Lawan, Ẹni ti Tinubu yan gẹgẹ bii igbakeji rẹ, to tun jẹ gomina ipinlẹ Borno tẹlẹ, Kashim Shettim, olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin tẹlẹ, Dimeji Bankọle wa nibi ipade ọhun.

Bakan naa ni awọn gomina ipinlẹ Borno, Gombe, Nasarawa ati Kebbi atawọn mi-in ni wọn wa nibi ipade ọhun, eyi to bẹrẹ ni bii aago mẹta ọsan.

Ṣugbọn ohun iyalẹnu lo jẹ pe oludije ẹgbẹ APC funpo aarẹ, Aṣiwaju Bọla Tinubu, ko si nibi ipade ọhun.

Leave a Reply