Faith Adebọla
Ẹgbẹ awọn Fulani darandaran lorileede yii, Miyetti Allah Cattle Breeders Association (MACBAN), ti kede pe ẹni tawọn yan laayo, tawọn si maa ṣatilẹyin fun lati de ipo aarẹ lọdun 2023 ni Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, wọn loun lawọn n fẹ loye.
Lasiko ipade kan ti ẹgbẹ naa ṣe niluu Abuja, lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, eyi tawọn olori Fulani darandaran lati ipinlẹ mẹrindinlogoji kaakiri orileede yii pesẹ si ni wọn ti sọrọ naa.
Ẹni to se kokaari ipade naa, Alaaji Ya’u Haruna, sọ lẹyin ipade ọhun pe, ‘‘a ti n ṣakiyesi awọn eeyan ti wọn n sọ pe awọn fẹẹ dupo aarẹ lọdun 2023, a si ti n ṣayẹwo wọn, Bọla Tinubu lo lewaju ninu ayẹwo ta a ṣe, tori oun lo ba wa da si ọrọ wa nigba to fi wa nipo gomina Eko, ati nigba ti awuyewuye waye laarin awa atijọba ipinlẹ Benue lọjọsi.
“Tinubu diidi gbera lati Eko, o wa si Benue, o pe wa jọ, o ba tọtun-tosi sọrọ, o si pẹtu saawọ naa, o ba wa yanju iṣoro ọhun nigba yẹn. A gbagbọ pe eeyan to le ṣeru nnkan yii, iru ẹni bẹẹ lo yẹ ko wa nipo aarẹ ilẹ wa, tori yoo ṣe ju bẹẹ lọ to ba dori aleefa.
“Ọpọ eeyan lo n foju ọdaran paraku wo awa Fulani ni Naijira. A o sọ pe ko si Fulani to n lọwọ si jiji maaluu gbe, jiji eeyan gbe, ifẹmiṣofo ati awọn iwa palapala bẹẹ, ṣugbọn eyi to pọ ju lọ ninu wa lo n gbe igbe aye alaafia, ti okoowo wa si mọyan lori, gbogbo wa kọ lọdaran. Aarẹ ti yoo gbe ẹtọ ọmọniyan awa Fulani larugẹ la fẹ.”
Bẹẹ lolori awọn Fulani ọhun, Haruna, sọ.