Tinubu loun faramọ bi Sanwo-Olu ṣe fagile owo ifẹyinti awọn gomina Eko

Aderounmu Kazeem

Bi gomina ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Babajide Sanwo-Olu, ṣe fopin si sisan owo oṣu fawọn gomina to ti kuro nipo l’Ekoo, Aṣiwaju Bọla Tinubu ti sọ pe igbesẹ to dara ni, bẹẹ lo dun mọ oun ninu daadaa.

Tinubu, lori ikanni abẹyẹfo ẹ, sọ pe igbesẹ akin ni gomina naa gbe, bẹẹ loun fọwọ si i daadaa, ati pe yoo jẹ ohun idunnu ti gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ba le gbaruku ti Babajide Sanwo-Olu, lori igbesẹ tuntun yii.

Ti ẹ o ba gbagbe, lọdun 2007 ti Bọla Tinubu pari saa keji ẹ gẹgẹ bii gomina l’Ekoo lo buwọ lu iwe abadofin kan, eyi ti yoo maa fun awọn gomina ti wọn ba ti n kuro nipo apaṣẹ l’Ekoo lanfaani nla lati maa gba owo rẹpẹtẹ lọdun.

Lara ohun ti wọn yoo tun lanfaani si ni mọtọ tuntun mẹfa lọdun mẹta-mẹta, bẹẹ ni wọn yoo tun kọ ile awoṣifila fun gomina bẹẹ nibi to ba wu u l’Ekoo ati l’Abuja. Ọlọpaa yoo wa ti a maa ṣọ wọn, awọn oṣiṣẹ naa yoo tun wa ti wọn a maa ṣiṣẹ nile wọn, ijọba Eko ni yoo si maa sanwo naa. Eyi ati ọpọ anfaani ni Tinubu bu ọwọ lu, bẹẹ lo si ti wa latigba yẹn.

Ofin ti Tinubu ṣe yii ni Babajide Sanwo-Olu sọ pe o-to-gẹẹ, ko yẹ ki awọn to ba ti kuro nipo tun maa gba aduru owo bẹẹ lapo ijọba Eko, paapaa niru asiko yii tawọn janduku ti ba nnkan rẹpẹtẹ jẹ l’Ekoo, bẹẹ nipinlẹ ọhun nilo owo rẹpẹte fun atunṣe ọpọ nnkan.

Leave a Reply