Monisọla Saka
Oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Tinubu ati iyawo rẹ, Olurẹmi, ti ranṣẹ ibanikẹdun si David Adeleke, ọdọmọkunrin olorin taka-sufee ti ọmọ rẹ ku lojiji lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹwaa yii.
Lori ikanni abẹyẹfo rẹ (twitter), lo ti sọrọ ikẹdun naa pe oun ba Davido ati Chioma kẹdun iku ojiji to pa ọmọ wọn, o gbadura pe ki Ọlọrun fun wọn ni idalọkanle lasiko iṣẹlẹ ibanujẹ yii.
Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwoolu ti ranṣẹ ibanikẹdun si ọmokunrin olorin yii. Ninu ọrọ ibanikẹdun naa lo ti kọ ọ pe ‘‘Iku maa n fi ọgbẹ ọkan ti ko si ọrọ kan to le jina rẹ sọkan eeyan. Lonii, mo n ba Davido ati Chioma daro lori iku ọmọ wọn.
Ko si ani-ani nibẹ pe gbogbo mọlẹbi lo fẹran Ifeanyi, mo gbadura pe ki Ọlọrun to dara fun wọn ni okun, bi wọn ṣe n la asiko to nira yii kọja.
‘Ọkan mi ati adura mi n ba yin lọ’.
Bẹẹ ni Sanwoolu pari ọrọ ibanikedun rẹ.
Lojiji ni ariwo gba gbogbo ilu pe, Ifeanyi, ọmọ ọdun mẹta to jẹ ọmọ ọkunrin olorin taka-sufee yii ku lojiji. Inu omi iwẹ atọwọda to wa nile wọn ni Banana Island lo ku si.
A gbọ pe iya ati baba ọmọ naa ko si nile lasiko iṣẹlẹ yii, ilu Ibadan ni ọn lọ fun eto kan.