Tinubu sọrọ sijọba Buhari, o lawọn ni wọn da gbogbo eleyii silẹ

Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Oloye Bọla Ahmed Tinubu ti sọrọ lile si awọn ti wọn n ṣejoba Buhari yii, o ni gbogbo ohun to ṣẹlẹ yii pata, awọn ni wọn da a silẹ. Baba naa sọ bayii pe: “Mo fẹẹ fi asiko yii fẹsun kan ijọba wa paapaa, ohun to ṣẹlẹ yii, awọn ni wọn da a silẹ, nitori wọn ko tete ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe lasiko, ko too di pe ọrọ naa burẹkẹ. To ba jẹ ijọba tete ba awọn ọdọ yii sọrọ ni, ti wọn tu wọn ninu, pẹlu ẹjẹ lati ṣe ohun ti wọn n fẹ fun wọn, ko le le to bayii rara!’

Lati orilẹ-ede Faranse ni Tinubu ti n ba awọn oniroyin tẹlifiṣan Channels sọrọ lori tẹlifoonu, nigba ti awọn yẹn wa a kan, ti wọn si n bi i leere ohun to mọ nipa ohun to ṣẹlẹ ni alẹ ijẹta, nibi tawọn ṣọja ti doju ibọn kọ awọn ọdọ ti wọn n ṣe iwọde jẹjẹ wọn. Ọga awọn oloṣelu naa ni oun ko lọwọ si ohun tawọn ṣọja ṣe yii, oun ko si le lọwọ si iru ẹ rara, nibi ti wọn yoo ti ta ẹjẹ alaiṣẹ silẹ, nigba ti ki i ṣe pe wọn ṣe kinni kan fun won. Tinubu ni bi ijọba yoo ba ṣe e daadaa ni, ki wọn tete wa ọga ṣọja, tabi ẹni yoowu to pa aṣẹ fun awọn ṣọja to jade yii, ki wọn si mu un, ki wọn fiya to tọ jẹ ẹ loju gbogbo aye.

Aṣiwaju Tinubu ni oun kọ loun ni too-geeti (Toll-gate) to wa ni Lẹki ti wọn n darukọ oun mọ yii, bẹe ni oun ko ni kọbọ kan ninu rẹ, ṣugbọn awọn eeyan kan ni wọn n gbe ọrọ naa kiri pe toun ni ibẹ n ṣe. O ni oun tun sọ ọ lẹẹkan si i pe oun ko ni i lọwọ si pipa awọn ọdo ọmọ Naijiria laye oun, nitori ohun ti ko dara ni.

Leave a Reply