Tinubu ta si Buhari: Ẹ gbepo pamọ, ẹ gbe Naira pamọ; a maa dibo, a maa wọle

Faith Adebọla

Yoruba bọ, wọn ni lowe-lowe laa lulu agidigbo, ọlọgbọn ni i jo o, ọmọran ni i mọ ọn. Owe yii lo wọ ọrọ ti oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu sọ lori ọwọngogo epo bẹntiroolu to n han awọn ọmọ orileede yii leemọ lasiko yii, ati awuyewuye to n lọ lori ipaarọ owo Naira wa ati si awọn owo tuntun ti wọn ṣẹṣẹ ko jade. Tinubu ni gbogbo iṣẹlẹ yii ye oun bo ṣe n lọ o, o ni ọtẹ lo wa nidii ẹ, tori ete lati da ibo gbogbogboo to wọle de tan yii ru lọrọ naa fi ri bẹẹ, o l’Ọlọrun o si ni i fun wọn ṣe.

Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹri naa sọrọ yii lọsan-an Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun ta a wa yii, nibi ayẹyẹ eto ipolongo ibo funpo aarẹ rẹ, eyi to waye ni papa iṣere Moshood Abiọla Stadium, to wa ni Kutọ, niluu Abẹokuta, ti i ṣe olu-ilu ipinlẹ Ogun.

Tinubu, tinu ẹ n du ṣinkin bo ṣe n sọrọ, to tun n danu duro fun orin Fuji ti Wasiu Ayinde K1 fi n kin ọrọ ẹ lẹyin lẹẹkọọkan, sọ pe:
“Ẹẹ baa parọ inki ara Naira, ibi tẹ ẹ ba gboju si, ọna ko ni i gbabẹ. Awa la maa wọle.”

O tun ni, “ẹ gbe’po pamọ, ẹ ko Naira pamọ, a maa dibo, a maa wọle, a maa dibo, a maa wọle. City boy, o ti de ba yin, mi o ki i ṣe alejo, ọmọ ile ni mi, mi ti de, oju o ni i ti yin, a maa gbajọba yii lọwọ wọn, awọn ọlọtẹ.”

Bakan naa ni Tinubu tun rọ awọn olugbọ rẹ pe: Ti wọn ba sọ pe ko sepo, a maa fẹsẹ wa rin lọọ dibo. Ẹlẹtan ni wọn, wọn le sọ pe ko sepo, wọn ro pe awọn le fi ọrọ epo da wahala silẹ, wọn n ko epo pamọ. Epo ibaa wa, ibaa ma si, ọkada ibaa wa, ibaa ma si, kẹkẹ Marwa ibaa wa, ibaa ma si, a maa jade lọọ dibo, a dẹ maa wọle. Ayipada dandangbọn to ga ju leyi, ẹ jẹ ki n sọ fun yin, o yẹ kẹẹ ti mọ nnkan ti mo ni lọkan. Gbogbo yin lẹ mọ mi, a n lọ sibẹ yẹn lati jawe olubori ni.”

Bayii ni Tinubu ṣe sọrọ naa…

Oriṣiiriṣii ọrọ lawọn eeyan ti n sọ lori oko ọrọ ti Tinubu ju yii, ọpọ lo si gba pe Aarẹ Muhammadu Buhari ati iṣejọba rẹ ni Tinubu n fohun ranṣẹ si, bo tilẹ jẹ pe o n darukọ ẹgbẹ Alaburada, iyẹn PDP, ṣugbọn ki i ṣe PDP lo ṣofin pipaarọ owo Naira, bẹẹ ni ki i ṣe PDP lo wa lori aleefa ti Tinubu sọ p’awọn maa gbajọba naa lọwọ wọn.

Tinubu fẹrẹ ma ti i pari ọrọ rẹ ọhun ti Oludari eto iroyin ninu igbimọ ipolongo ibo aarẹ rẹ, Oloye Fẹmi Fani-Kayọde, to ti figba kan jẹ minisita feto irinna ofurufu, fi gba ori ikanni tuita rẹ lọ, toun naa si kin ọga rẹ lẹyin, o ni:
“Ohun yoowu tẹ ẹ n gbero lati ṣe kẹ ẹ le dabaru eto idibo to n bọ yii, ibaa jẹ nipasẹ owo Naira tuntun ni o, abi ọwọngogo epo ni o, abi ti ẹru tẹ ẹ fẹ da ba awọn araalu ti ọkan wọn o ni i balẹ, ijakulẹ ni gbogbo ẹ maa ja si.

“Afẹfẹ ti fẹ, a ti ri furọ adiẹ o. A ti mọ ero yin. A ti mọ awọn tẹ ẹ fẹẹ lo. A mọ awọn to wa lẹyin gbogbo ẹ. A si ti mọ nnkan ta a maa ṣe.”

Amọ, agbẹnusọ fun eto ipolongo ibo aarẹ lẹgbẹ PDP, Amofin agba Daniel Bwala, lori ikanni tuita rẹ, sọ pe: “wọn fẹẹ yọ alaga ajọ eleto idibo INEC, ko ṣee ṣe, wọn tun kọju ija si ọga agba banki apapọ CBN lati yọ ọ nipo, wọn o riyẹn naa ṣe, ni wọn ba mugbe bọnu bii eku to ha sinu iho ara ẹ.”

O tun kọ ọ sibẹ pe: “Nigba ti mo sọ fun yin pe gbogbo ọrọ to wa lẹnu wọn ti wọn fẹẹ ba araalu sọ nipa nnkan ti wọn maa ṣe lori aleefa ko ju pe wọn nigbagbọ ninu ijọba to wa lode yii lọ, ẹ ni ko ri bẹẹ. Ni bayii ti Aarẹ (Buhari) ti loun o ni i gba lati ran wọn lọwọ ki wọn ribi ṣe magomago eto idibo idibo, wọn ti bẹrẹ si i gbogun ti Aarẹ o.”

Bẹẹ loun naa sọ.

Leave a Reply