Faith Adebọla
Minisita agba lori ọrọ iṣe atawọn oṣiṣẹ, Amofin agba Festus Keyamọ, ti fesi si awuyewuye to n lọ nigboro nipa Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti wọn n beere ibi to wa ati ohun to da a duro sẹyin odi. Keyamọ ni kawọn eeyan lọọ dakẹ ariwo o, tori bi Tinubu wa nile o, bi ko si si nile o, oun lo maa di aarẹ Naijiria lọdun to n bọ.
O tun ni ọgbọn-inu lawọn fi aisi nile Tinubu da, tori ohun a ba bo ni i niyi, o lawọn fẹẹ fi ọrọ naa ru awọn alatako loju ni, awọn fẹ ki wọn maa mefo lasan ni, awọn si mọ ohun tawọn n ṣe.
Lori ikanni ayelujara tuita rẹ lo ti sọrọ yii laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keji, oṣu Kẹwaa yii.
Ṣe ṣaaju asiko yii lawọn eeyan ti n sọ oriṣiiriṣii ọrọ nipa bi oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ọhun, Bọla Tinubu, ṣe di afẹku bii imi eegun lati ọsẹ kan aabọ sẹyin. Gẹrẹ ti baba naa lọ siluu oyinbo ni awọn kan gbe e sori ẹrọ ayelujara pe ara Tinubu ti ko ya lo jẹ ko pada si London, wọn lo lọọ gba itọju ni, bo tilẹ jẹ pe ohun tawọn agbẹnuṣọ rẹ n sọ ni pe awọn ipade ati ifikun lukun pataki kan lo tori ẹ lọ.
Ohun to ya ọpọlọpọ lẹnu ni bi Tinubu ko ṣe wale, bẹẹ ni ko yọju si apero adehun alaafia ti ẹgbẹ kan n ṣe fawọn oludije funpo aarẹ, oun nikan lo ran igbakeji ẹ, Kashim Ṣhetima lati ṣoju fun un.
Bakan naa lo jẹ igbakeji rẹ yii lo ṣoju fun un lasiko ayẹyẹ ajọdun ọdun kejilelọgọta ti Naijiria gbominira, eyi to waye l’Abuja.
Ọrọ yii ti n mu kọpọ eeyan kọminu si ipo ti ilera Tinubu wa, niṣe lawọn eeyan n sọ pe ilera baba naa ko gbe ohun to n naga fun, iyẹn didi aarẹ orileede yii.
Ṣugbọn Keyamọ, to jẹ agbẹnusọ igbimọ to n polongo ibo fun Tinubu ati Shettima lati di aarẹ ni wiwa nile tabi aisi nile Tinubu ko ṣe nnkan kan.
“Boya o wa nile o, tabi ko si nile, ẹru lo n ba wọn. Tinubu ti di ẹrujẹjẹ baba ijaya fun wọn ni. Bi wọn ṣe n beere ibi to wa, wọn fẹẹ mọdi abajọ ni.
Ọgbọn-inu kan lagbo oṣelu lo jẹ lati mu kawọn alatako maa mefo. Ko si nile lasan, Tinubu di orin ti wọn n kọ, bẹẹ aarẹ Naijiria to n bọ niyẹn,’ gẹgẹ bo ṣe wi.