Tirela Dangote fi oju ọna rẹ silẹ, lo ba tẹ ọlọkada atero pa n’Ibeṣe

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ka ni ọwọ awọn ero ti inu n bi si dẹrẹba kan to wa tirela Dangote lagbegbe Ibeṣe, lọjọ Ẹti to kọja yii tẹ ẹ ni, o daju pe inu tirela rẹ ti wọn dana sun naa ni wọn ko ba jo oun naa nina mọ pẹlu, nitori bo ṣe fi oju ọna rẹ silẹ, to lọọ doju kọ ọlọkada to n bọ jẹẹjẹ, to si tẹ ọkunrin naa ati ero to gbe sẹyin pa.

Ijọba ibilẹ Ariwa Yewa ni Ibeṣe wa, nipinlẹ Ogun. Awọn tirela Dangote pọ nibẹ nitori ileeṣẹ simẹnti ọkunrin naa to wa lagbegbe ọhun.

Alaye ti Alukoro TRACE, Babatunde Akinbiyi, ṣe fawọn akọroyin ninu atẹjade to fi kede iṣẹlẹ naa laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ni pe dẹrẹba to wa tirela yii lo jẹbi.

O ni awọn eeyan tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe iwakuwa ni awakọ to wa tirela naa n wa, bo ṣe gun gbọọrọ to naa lo ṣe n sare buruku. Nigba to si ya lo kuro loju ọna tiẹ, o kọju si ọlọkada to n bọ lodi-keji ọna, nigba naa lo si kọ lu wọn, to run wọn jegejege. Koda, ko ṣee wo o fẹni ti ko ba lọkan, o buru gan-an.

Bi awakọ tirela yii ṣe ri i pe oun ti paayan meji lo kan lugbẹ, o sa lọ raurau ni. Ai ri i mu naa lo jẹ kawọn eeyan binu sọna si tirela to fi paayan naa, wọn jo o gidi.

Ile igbokuu-si to wa l’Ọsibitu Jẹnẹra Ilaro ni wọn gbe oku ọkan ninu awọn eeyan meji naa si, nigba tawọn mọlẹbi ẹni keji ti gba oku ẹ, wọn si ti sin in pẹlu.

Leave a Reply