Tirela Dangote pa ọmọleewe n’Ilaro, lawọn eeyan ba dana sun un

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹfa yii, ni ọmọleewe kan to jẹ akẹkọọ nileewe Baptist High School, Ilaro, padanu ẹmi ẹ.

Tirela ileeṣẹ Dangote kan lo gba akẹkọọ ọlọdun kin-in-ni nipele akọkọ naa (JSS 1), to si pa a loju-ẹsẹ. Dẹrẹba to wa ọkọ ọhun sa lọ ni, wọn ko ri i mu.

Awọn eeyan ko tiẹ kọkọ dana sun tirela naa, wọn kan fọ gilaasi rẹ ni. Ṣugbọn nigba ti ibinu ru bo awọn mi-in loju ninu wọn ni wọn pada sọna si tirela to ko simẹnti naa.

Nnkan bii aago meji ọsan ku iṣẹju mẹjọ niṣẹlẹ buruku yii waye gẹgẹ bi ọkan lara awọn to kọkọ gbe e sori ayelujara Fesibuuku ṣe sọ.

Ninu fidio kan ti wọn fi sori ayelujara, niṣe lawọn eeyan kan gun ori tirela naa, ti wọn bẹrẹ si i ja simẹnti to ko silẹ, ki wọn too sọna si i, to si bẹrẹ si i jona gidi. Agbegbe Sabo ni wọn ni iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.

Laarin ọsẹ kan sira wọn, tirela ileeṣẹ Dangote meji lawọn eeyan ti fibinu sọna si, nitori bawọn ọkọ naa ṣe n gba ẹmi awọn ti ko ṣẹ wọn lẹṣẹ kan si ni.

Iṣẹlẹ akọkọ ni ti tirela Dangote to fi ọna rẹ silẹ lọsẹ to kọja yii, n’Ibeṣe, to lọọ doju kọ ọkada to n bọ lodikeji ọna, to si pa ọlọkada naa atẹro to gbe.

A gbọ pe awọn ọlọpaa ti n kapa rogbodiyan to ṣẹlẹ ni ti ẹlẹẹkeji yii naa, wọn si ti da awọn to n binu naa lẹkun.

Leave a Reply