Tirela elepo ṣubu ni Badagry, lawọn eeyan ba n fi koroba gbọn epo bẹntiroolu

Aderounmu Kazeem

Bi onikoroba ṣe n gbe e, bẹẹ lawọn to yọ ike lọwọ paapaa n sare lẹlẹlẹ lọ sibi ti mọto tanka epo bẹtiroolu kan ṣubu si lowurọ kutu oni Tusidee yii lagbegbe Igborosun, ni Aso Odo, niluu Badagry l’Ekoo.

Ohun ti ALAROYE gbọ ni pe, lojiji ni tanka epo to gbe lita bii ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn yii ṣubu lulẹ, ti awọn eeyan si berẹ si gbọn ọn laibikita ijamba ina to le ṣẹlẹ nibẹ.

Ọgbẹni Olufẹmi Oke Ọsanyitolu to jẹ ọga agba fun iṣẹlẹ pajawiri l’Ekoo ti sọ pe lojuẹsẹni wọn ti fi iṣẹlẹ ọhun to awọn leti lawọn ti sare debẹ.

Bakan naa lo ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn eeyan kan ṣe n gbọn epo to n jo danu, o ni ọpọlọpọ igba ni irufẹ iwa bẹẹ ti ṣe ẹmi ọpọ eeyan lofo, ati pe awọn to n gbọn epo to n jo danu yii, bii ẹni pe wọn ko nifẹẹ ara wọn rara ni.

Ohun ta a gbọ ni pe, ọkọ tanka agbepo mi-in ti debẹ, ti wọn si ti n fa epo sinu ẹ, bẹẹ lawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ to n mojuto awọn iṣẹlẹ pajawiri naa ti duro wamuwamu lati le tete mojuto ijanba to le ṣeeṣi waye.

Leave a Reply