Tirela kọ lu bọọsi n’Ijẹbu-Ode, lo ba pa eeyan mẹrin lẹsẹkẹsẹ

    Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ere buruku ti tirela kan n sa loju ọna Ijẹbu-Ode/ Oru, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kọkanla yii, lagbara to bẹẹ to jẹ o fi oju ọna rẹ silẹ, o si sọda soju opo keji, lo ba kọ lu bọọsi to n bọ jẹẹjẹ ẹ, o si pa awọn mẹrin to wa ninu ọkọ naa.

Nnkan bii aago kan ọsan kọja iṣẹju mẹẹẹdogun ni ijamba yii ṣẹlẹ, gẹgẹ bi Alukoro TRACE, Babatunde Akinbiyi, ṣe wi. O ṣalaye pe obi lo wa ninu bọọsi to n bọ jẹẹjẹ rẹ lati Ibadan yii, tirela to ko ba wọn si n lọ si Ijẹbu-Ode.

Ṣugbọn nitori ere asapajude ti tirela naa n sa ni nnkan ṣe daru mọ dẹrẹba rẹ lọwọ, to fi lọọ pa awọn obinrin oniṣowo obi mẹta to wa ninu bọọsi naa, pẹlu dẹrẹba to n wa wọn bọ.

Ni ti dẹrẹba tirela to da walaha silẹ yii, oun ko ku, o kan fara pa ni. Bẹẹ naa si ni ẹni ti wọn jọ wa ninu mọto naa ko ku, oun naa farapa ni.

Mọṣuari Ọsibitu Jẹnẹra Ijẹbu-Ode ni wọn ko awọn oku mẹrin naa lọ gẹgẹ bi Akinbiyi ṣe wi, o ni ileewosan yii kan naa ni dẹrẹba tirela ati ẹni keji ẹ naa ti n gba itọju.

Ọga patapata fawọn TRACE, Ṣeni Ogunyẹmi, ba ẹbi awọn eeyan to doloogbe lojiji naa kẹdun, Bẹẹ lo kilọ fawọn awakọ to n wa tirela atawọn mi-in pe ki wọn yee sare buruku loju popo.

 

Leave a Reply