Tirela wo lu ọkọ ayọkẹlẹ l’Orimẹrunmu, lo ba tẹ dẹrẹba pa

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Tirela kan ti gaasi wa ninu rẹ, padanu ijanu ẹ laaarọ ọjọ Satide, ọjọ kẹrinla, oṣu kẹjọ yii, ni marosẹ Eko s’Ibadan. Bo ṣe wo lu mọto ayọkẹlẹ meji niyẹn, to si pa ọkunrin kan sinu ọkan ninu awọn mọto meji naa.

Orimẹrunmu gan-an niṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ, loju ọna marosẹ yii. Ohun ti Babatunde Akinbiyi, Alukoro TRACE, sọ ni pe ni nnkan bii aago mẹjẹ kọja iṣẹju mẹta aarọ ni ijamba yii waye.

Akinbiyi ṣalaye pe tirela to kun fun afẹfẹ idana ọhun ko ni nọmba kankan, awọn kaa to wo lu lo ni nọmba. O ni Toyota Corolla ti nọmba ẹ jẹ EQ 165 LSR ati Sienna ti wọn kọ FKJ 341 GC si lara ni tirela yii wo lu.

Alukoro TRACE tẹsiwaju pe niṣe ni awakọ to wa tirela naa padanu ijanu ẹ, ohun to jẹ ko ṣubu le awọn mọto meji naa lori niyẹn.

O tẹsiwaju pe ọkan ninu awọn ọkunrin to wa ọkọ ayọkẹlẹ meji naa lo doloogbe, nibi ti tanka epo wo pa a si.

Nigba tawọn ti iṣẹlẹ yii ṣoju wọn n sọrọ, wọn ni tirela to gbe gaasi yii ko deede ṣubu, wọn ni ere buruku lo n sa bọ tẹlẹ.

Wọn fi kun un pe baba, iya atawọn ọmọ wọn meji ti wọn jẹ ọmọde ni wọn jọ wa ninu mọto Toyota Corolla, nigba ti dẹrẹba ati awọn obinrin meji wa ninu ọkọ Sienna. Wọn ni  nnkan kan ko ṣe awọn to wa ninu Sienna, wọn ko fara pa paapaa. Afi baba to wa Corolla nikan lo dagbere faye.

Ohun to dun awọn eeyan bi wọn ṣe wi ni pe awakọ to wa tirela naa sa lọ, ko sẹni to ri i mu lẹyin tijamba ọhun waye tan.

Wọn ti gbe oku baba to ku ninu Corolla lọ si mọṣuari ọsibitu Famobis, ni Lotto, loju ọna marosẹ yii kan naa.

Leave a Reply