Faith Adebọla
Aarẹ orileede yii, Bọla Ahmed Tinubu, to n jẹjọ lọwọ lori ijawe olubori rẹ ninu eto idibo sipo aarẹ to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, ti ko awọn iwe-ẹri, iyẹn sabukeeti to gba ni Fasiti Chicago kan, Chicago State University, nilẹ Amẹrika lọhun-un kalẹ niwaju igbimọ to n gbọ awuyewuye to su yọ lori eto idibo sipo aarẹ, Presidential Election Petition Court, gẹgẹ bii ẹri pe loootọ loun kawe nileewe naa, oun o si purọ sabukeeti mọ ara oun rara.
Lọsan-an ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrin, oṣu Keji, ta a wa yii, nigba ti igbẹjọ n tẹsiwaju lori awọn ẹsun ti wọn fi kan Tinubu, ni agbejọro rẹ, Amofin agba Wọle Ọlanipẹkun, ko awọn iwe naa kalẹ, Tiribuna si gba a wọle.
Amọ ki i ṣe wọọrọwọ bẹẹ naa ni wọn gba awọn iwe-ẹri yii wọle latari bi olupẹjọ kin-in-ni, Alaaji Atiku Abubakar, ati ẹgbẹ oṣelu rẹ, Peoples Democratic Party ṣe ta ko awọn iwe-ẹri naa, wọn ni ayederu lasan ni.
Yatọ si sabukeeti rẹ, lara awọn iwe fasiti ọhun ti wọn ko kalẹ ni akọọlẹ ‘mo wa kilaasi loni-in’, ẹri pe Tinubu gboye jade, o si ṣe giradueṣan nibẹ, ati lẹta kan ti wọn loun ni wọn fi gba olujẹjọ yii wọle, iyẹn Admission letter, sileewe naa.
Ẹ oo ranti pe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, ni Tinubu, nipasẹ awọn lọọya rẹ, ti bẹrẹ si i ro arojare lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an lọlọkan-o-jọkan.
Yatọ sawọn iwe-ẹri wọnyi, Ọlanipẹkun tun ko awọn ẹda iwe iwọluu onibaara rẹ, ti wọn n pe ni US Visa, eyi tọkunrin naa fi n wọle-jade lorileede Amẹrika laarin ọdun 2011 si 2021 kalẹ.
Awọn ẹsibiiti wọnyi jẹ lati fi ro arojare pe Tinubu ko lẹbọ lẹru kankan, ko si si apẹẹrẹ ọdaran tabi arufin kan lara rẹ, tori bo ba je bẹẹ ni, wọn o ni i faaye gba a lati maa lọ maa bọ lati orileede kan somi-in ni gbogbo asiko wọnyẹn, bẹẹ lawọn aṣọbode o ni i maa fontẹ jan pali rẹ gbogbo.
Tinubu tun ṣafihan lẹta kan ti Ẹmbasi ilẹ Amẹrika kọ si ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa lọjọ kẹrin, oṣu Kẹrin, ọdun 2003, ni ifesipada si lẹta tawọn agbofinro kọ silẹ Amẹrika nipasẹ ẹmbasi wọn pe awọn fẹẹ fidi ootọ mulẹ nipa iwe-ẹri ọkunrin ti wọn n pe ni Jagaban yii.
Bakan naa ni wọn tun ko awọn iwe ipẹjọ kan kalẹ, eyi to fihan pe awọn amofin agba lawọn ipinlẹ Adamawa, Akwa Ibom, Bayelsa, Delta, Edo ati Sokoto ti pe Tinubu lẹjọ ri lori ẹsun kan naa to da lori awọn iwe-ẹri rẹ yii lasiko ti ọkunrin naa fẹẹ dupo aarẹ, ko tun yẹ kọrọ iwe-ẹri tun maa ja ranyin gẹgẹ bii ẹjọ tuntun, agbọrin eṣi lawọn to pe ẹjọ naa ṣi n jẹ lọbẹ.
Gbogbo awọn iwe-ẹri yii ni kootu naa gba wọle, wọn ni gbogbo ẹ lawọn maa tan’na wo lawotunwo daadaa bi igbẹjọ ṣe n lọ. Lẹyin eyi ni Alaga igbimọ naa, Onidaajọ Haruna Simon Tsammani, sun igbẹjọ to kan si ọjọ keji, iyẹn Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karun-un, oṣu Keje yii.