Tọọgi to ba tun lu aṣoju ijọba l’Ọyọọ yoo jiyan rẹ niṣu- Ọjọmọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori bi awọn tọọgi ṣe ya lu awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Ọyọ l’Ojọbọ, Tọsidee, to kọja, ti wọn si ṣe mẹrin lẹse ninu wọn, oludari ajọ to n mojuto pipa ofin eto imọtoto ayika mọ nipinlẹ naa, ACP  Ọjọmọ Francis, ti kilọ fawọn ọmọ iṣọta lati ma ṣe da iru aṣọ laṣa mọ, o ni ẹni to ba tun dan iru ẹ wo yoo kan iyọnu.

Ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, lawọn ọmọ aye ya lu awọn oṣiṣẹ àjọ kólẹ̀-kódọ̀tí labẹ biriiji Mọlete to wa lẹgbẹẹ ile Oloye Lamidi Adedibu, agba oṣelu ilẹ Ibadan to ti ṣilẹ bora bii aṣọ.

Bi ko ṣe pe awọn oṣiṣẹ ijọba naa yara kó sinu mọto wọn, ti wọn si fere ge e, awọn ẹruuku ko sọ pe awọn ko lu wọn pa patapata. Sibẹ naa, mẹrin ninu wọn lawọn ọmọ aye lu ṣe leṣe to jẹ pe awọn ti ori ko yọ ninu wọn lo sare gbe wọn lọ sileewosan ijọba fun itọju.

Ki i kuku ṣe pe awọn agbofinro wọnyi kọja aaye wọn, ẹnu iṣẹ ni wọn wa, wọn n fi panpẹ ọba gbe awọn ọbun eeyan to n dalẹ̀ sinu àgbàrá lasiko ojo to ṣẹṣẹ rọ da laaarọ ọjọ naa ni.

Lopin ọsẹ yii ni ACP Ọjọmọ, ẹni to ti fẹyinti lẹnu iṣẹ ọlọpaa bu ẹnu atẹ lu igbesẹ awọn tọọgi naa, o ni ko si orukọ meji ta a le pe iwa naa ju pe wọn foju tẹnbẹlu ijọba lọ.

 

O waa kilọ pe bi ẹnikẹni ba tun na aṣoju ijọba ipinlẹ Ọyọ lọjọ iwaju, oluwarẹ yoo jẹ iyan ẹ niṣu, yatọ si pe awọn yoo fi panpẹ ọba gbe e, yoo tun jiya to lagbara labẹ ofin.

Leave a Reply