‘To ba fi maa di ọdun 2023, ẹgbẹ APC yoo ti run Naijiria womuwomu’

Faith Adebọla

Awọn agbaagba ilẹ Hausa ti wọn wa ninu ẹgbẹ Northern Elders Forum (NEF) ti figbe bọnu, wọn ni pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, ti ko ba si ayipada, o da awọn loju pe ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC) to n ṣakoso lọwọ yii yoo ti run Naijiria womuwomu to ba fi maa di ọdun 2023 ti gbogbo eeyan n foju sọna fun.

Agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Ọmọwe Hakeem Baba-Ahmed lo sọrọ yii lori eto tẹlifiṣan Channels kan lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lorukọ ẹgbẹ naa.

Ẹgbẹ naa di ẹbi ipo ti orileede yii wa ru awọn oloṣelu, o lawọn ni wọn fa a, ati pe aisi aabo to peye, to mu ki awọn janduku agbebọn ati ajinigbe maa jaye ọlọba ko ṣadeede ṣẹlẹ, awọn oloṣelu lo ti jẹ ki nnkan wọ latilẹ.

O ni ere ti awọn ẹgbẹ oṣelu n sa bayii ko kọja bi wọn ṣe fẹẹ jawe olubori ninu eto idibo gbogbogboo lọdun 2023, wọn o tiẹ ronu bi wọn ṣe fẹẹ tun orileede yii ṣe ko too di ọdun naa.

“Kin ni wọn fẹẹ ṣe lọdun 2023, leyii to jẹ pe laarin ọdun kan aabọ to ku yii, ẹgbẹ oṣelu APC yoo ti fẹyin Naijiria janlẹ, ṣe orileede ti wọn ti maa run womuwomu leeyan fẹẹ ṣe nnkan kan si, bẹẹ ẹgbẹ oṣelu PDP lo bi APC.

‘‘Fun apẹẹrẹ, a ti ri mọkumọku ti APC n ṣe lọwọ, ṣugbọn eto to ṣe gunmọ wo lẹ ri lọdọ ẹgbẹ mi-in nipa ipese iṣẹ, atunṣe ọrọ-aje ati okoowo, tabi ti ọrọ eto aabo to mẹhẹ. Ko si.”

Bakan naa ni Baba-Ahmed sọ pe bawọn gomina ṣe n yọ fokifoki lati ẹgbẹ oṣelu kan si omi-in ko ya oun lẹnu, ko si sidii fun ẹgbẹ oṣelu PDP lati figbe ta lori eyi tori oun o ri iyatọ laarin ẹgbẹ oṣelu mejeeji, ọkan naa ni kan-un ni wọn, bi ẹnikan ṣe n bọ aṣọ PDP lọrun ti wọn n wọ ti APC, bẹẹ lawọn mi-in n fa ti APC ya, ti wọn n da agbada PDP.

Leave a Reply