To ba wu Ọlọrun, mo ṣetan lati dupo aarẹ orileede yii lọdun 2023– Tunde Bakare

Faith Adebọla

 Oludasilẹ ati adari ijọ Citadel Global Community Church, ti wọn n pe ni Latter Rain Assembly tẹlẹ, Pasitọ Tunde Bakare, ti sọ pe o wu oun lati jade dupo aarẹ orileede yii lọdun 2023, to ba jẹ ifẹ Ọlọrun ati tawọn ọmọ Naijiria pe koun ṣe bẹẹ.

Bakare sọrọ yii nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin ipade rẹ pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari ni Abuja, lọjọ Ẹti, Furaidee yii.

Ojiṣẹ Ọlọrun to ti figba kan dupo igbakeji aarẹ orileede yii pẹlu Buhari fesi nigba ti wọn bi i boya oun naa fẹẹ jade dupo lọdun 2023, pe:

“Gbogbo ọmọ Naijiria to ti dagba to, ti ko si lẹbọ lẹru, lo lominira lati dupo aarẹ. Bi orileede yii ṣe maa goke agba lo jẹ mi logun, to ba si wu Ọlọrun pe ki n ṣe bẹẹ, ti awọn ọmọ Naijiria naa fẹ bẹẹ, ki lo de ti mi o ni i dupo aarẹ? Ẹtọ ti gbogbo eeyan ni lemi naa ni lati jade dupo nigba ti mo ṣi wa laaye. Mo ti ṣe oluṣọ-aguntan ijọ fun ọdun mẹtalelọgbọn bayii, a ti mu awọn oludari tuntun jade, ohun ti mo fẹẹ pa ọkan mi pọ le lori ni bi orileede yii ṣe maa di atunkọ.

Ipo kan ṣoṣo pere ni ipo aarẹ, bẹẹ ọpọ nnkan mi-in wa ti a le ṣe lati ṣatilẹyin fun ẹnikẹni to ba wa nipo naa ki ọwọ aago orileede yii ma baa lọ sẹyin mọ, ko le maa lọọ siwaju lai sọsẹ, pẹlu awọn eeyan inu rẹ.

Mi o fọrọ sabẹ ahọn sọ fun Aarẹ Buhari, mo ti la erongba mi mọlẹ fun un, aarin emi ati ẹ lo wa, ko ju bẹẹ lọ”, bẹẹ ni Pasitọ Bakare wi.

Leave a Reply