Toheeb ati ọrẹ ẹ ki ọmọleewe girama mọlẹ l’Ekoo, ni wọn ba fa a nidii ya

Jide Kazeem

Adugbo kan niluu Ẹgan, l’Ekoo, ni awọn ọkunrin bii meloo kan tun ti ki ọmọde kan mọlẹ, ti wọn si fipa ba a lopọ

Ọmọleewe girama ipele akọkọ, kilaasi kẹta (JSS 3) ni wọn pe ọmọ ti wọn ṣe baṣubaṣu yii lopin ọsẹ to kọja yii.

Nibi ti ọrọ ọhun le de, wọn ni ọsibitu kan ni wọn sare gbe e lọ, nibi ti wọn ti ran abẹ ẹ to n ṣẹjẹ ṣuruṣuru, lẹyin tawọn ọbayejẹ yii fi kinni wọn fa a nidii ya pẹrẹpẹrẹ.

ALAROYE gbọ pe ọmọkunrin kan ti orukọ e n jẹ Toheeb Mustapha lo waa fọgbọn tan an kuro nile wọn ni adugbo Ọrẹ meji, lẹbaa ojuna Isuti, ni Ẹgan. Ile ileetura kan ti wọn pe ni ‘The Cool Tervan Hotel’ lo gbe e lọ, ati pe ko jinna sile awọn ọmọ naa pẹlu.

Nibi ti Toheeb, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Sir Small, atawọn ọrẹ ẹ ti n fipa ba ọmọ yii lo pọ ni ẹjẹ ti bẹrẹ si da lara ẹ, nigba ti wọn si n da a pada sile ni aṣiri ohun ti wọn ṣe fun un tu sita.

Awọn eeyan to ri i bi ẹjẹ ṣe n da lara ẹ yii ni wọn kọkọ fi ariwo ta, ohun ti wọn si ro ni pe boya awọn to gbe ọmọ naa ti lọọ fi ṣoogun ni.

Loju ẹsẹ lọwọ ti tẹ Toheeb ni tiẹ, ti ẹni keji ẹ ti wọn jọ fipa ba ọmọ naa lo pọ si ti sa lọ.

Sunkanmi, ẹni tawọn eeyan tun mọ si G33 ni wọn pe orukọ ẹni to sa lọ yii, wọn lo pẹ ti wọn ti maa n ṣeru nnkan bẹẹ laduugbo yẹn.

A gbọ pe nibi ti wọn ti n lu Toheeb lawọn ọlọpaa Igando ti debẹ, ti wọn si gba a lọwọ awọn ero to fẹẹ lu u pa yii.

Wọn ni lati nnkan bii ọjọ meloo kan sẹyin ṣaaaju iṣẹlẹ ọhun ni Sunkami ti gba yara kan kalẹ nileetura naa, ki wọn too tan an wa sotẹẹli ọhun.

Wọn ni Toheeb ti jẹwọ, o ni mẹkaniiki loun, ati pe latọdun 2018 loun ti gba nọmba ọmọ naa lọwọ ̀ọkan lara awọn ọmọ kilaasi rẹ, ti oun si maa n ba a sọrọ daadaa lori facebook. O lawọn ko lo ọmọ naa fi ṣoogun kankan, kinni awọn lo kan ṣe e leṣe labẹ.

Tẹ o ba gbagbe, ko ti i ju bii ọsẹ kan lọ ti awọn eeyan kan fipa ba ọmọ ọdun mọkanla kan sun lagbegbe yii kan naa, iyẹn ni Ejigbo, ti ọmọ naa si ku mọ wọn lọwọ.

 

Leave a Reply