Tọkọ-taya Ademẹhintoye rẹwọn he, ọmọ ọlọmọ ni wọn fẹẹ lọ fi ṣowo ẹru niluu oyinbo

Faith Adebọla, Eko

Tọkọ-taya kan niluu Eko, Ọgbẹni Peter Ademẹhintoye, ẹni ọdun mẹtadinlogoji, atiyawo ẹ, Abilekọ Abọsẹde Ademẹhintoye, ẹni ọdun mẹrindinlogoji, ti dero ahamọ bayii, wọn ni Ọlọrun lo ko ọmọbinrin kan, Adetula Oluwatosin, yọ lọwọ wọn, tori diẹ lo ku ki wọn ta a siluu oyinbo bii ẹru.

Ajọ to n gbogun ti aṣa kiko eeyan ṣowo ẹru (National Agency for the Prohibition of Trafficking in Persons, NAPTIP), lo wọ awọn afurasi ọdaran mejeeji naa lọọ ile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa n’Ikẹja, nipinlẹ Eko, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ibẹ ni wọn ti n jẹjọ ẹsun fifeeyan ṣowo ẹru, nile-ẹjọ naa ba sọ wọn sahaamọ.

Gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe ẹsun wọn (FHC/L/127c/2020), ẹsun mẹrin ti wọn fi kan wọn ni fifeeyan ṣowo ẹru, igbimọ-pọ lati huwa aidaa, jibiti lilu, ati pe wọn pera wọn ni ohun ti wọn ko jẹ.

Ọdun 2019 niṣẹlẹ naa waye, ni ṣọọbu kan to wa ni Ketu, ibẹ ni wọn ti pari eto lati fi Oluwatosin ranṣẹ sorileede Oman, bii ọmọọdọ ati ẹru.

Wọn tun fẹsun meji mi-in kan Abilekọ Ademehintoye pe lọjọ keji, oṣu kẹfa, ọdun yii, o pete bi ọkọ rẹ yoo ṣe gbọna ẹyin sa kuro lahaamọ NAPTIP to wa ninu ọgba GRA Ikẹja, nibi ti wọn fi i si, to si tun kọ lu si oṣiṣẹ ajọ yii kan, Ọgbẹni Olumide Foyinsọla, lẹnu iṣẹ ọba.

Gẹgẹ bi Agbefọba C. I. Ajeigbu ṣe wi, awọn ẹsun wọnyi ta ko isọri kejilelogun, ikẹrinlelogun, ikejidinlọgbọn ati ikejilelọgbọn iwe ofin ka feeyan ṣowo ẹru, ti ọdun 2015.

Bo tilẹ jẹ pe awọn olujẹjọ yii lawọn ko jẹbi, ti wọn si rawọ ẹbẹ pe kile-ẹjọ faye beeli silẹ fawọn, ṣugbọn ọrọ wọn ko ta leti Adajọ Olurẹmi Oguntoyinbo. Adajọ naa ni kawọn afurasi yii ṣi maa lọọ gbatẹgun lahaamọ ẹwọn titi di ọjọ kọkanla, oṣu to n bọ, koun too mọ boya wọn le gba beeli wọn tabi bẹẹ kọ.

Leave a Reply