Tọkọ-taya atọrẹ wọn to n jale epo diisu l’Agọṣaṣa bọ sọwọ ọlọpaa

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Owo to le ni miliọnu mẹjọ naira (8,162,750) ni awọn tọkọ-taya kan,  Adeniyi Stephen ati Adetọla Adeyinka,  ti ri nidii epo diisu ti wọn lọọ n ji fa lara ọpa ẹrọ alatagba ileeṣẹ Glo kan to wa  l’Agọṣaṣa, Ipokia, nipinlẹ Ogun, kọwọ palaba wọn too segi lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kejila yii.

Yatọ sawọn mejeeji yii, wọn tun mu ọkunrin kan torukọ ẹ n jẹ Ojo Sulaimọn mọra. Awọn mẹtẹẹta naa lọwọ si ti tẹ bayii.

Ẹnikan torukọ ẹ n Joseph Gaul Ekanem lo fi to awọn ọlọpaa Ipokia leti pe awọn ole kan n gbe mọto passat ti nọmba ẹ jẹ BNS 261 AAA, wa lati ji epo diisu ileeṣẹ Glo ọhun.

Nigba ti DPO Ipokia, SP Adebayo Akeem, atawọn ikọ ẹ bẹ̀rẹ̀ iwadii wọn, mọto ti wọn fi n waa gbe epo naa ni wọn kọkọ mu, ko si pẹ tọwọ fi ba tọkọ-taya Adeniyi ati Ojo to ṣikẹta wọn.

Ṣaaju ni iwadii awọn ọlọpaa ti fidi ẹ mulẹ pe oṣiṣẹ ileeṣẹ Glo naa ni Adeniyi Stephen, o si tun wa n ja ileeṣẹ to n sanwo oṣu fun un naa lole.

Ṣa, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, sọ pe ọga ooun, CP Edward Awolọwọ, ti ni kawọn gbe awọn tọkọ-taya yii atẹni kẹta wọn lọ si kootu laipẹ rara.

Leave a Reply