Tọkọ-tiyawo fẹẹ kọ ara wọn, ni wọn ba n ja sọmọ to da wọn pọ l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ibẹrẹ ifẹ dun, opin ifẹ nigba mi-in ni i koro bii jogbo.

Nigba ti Kẹmi Fatogun n fẹ Uhuo Elias ni nnkan bii ọdun mẹjọ sẹyin, ko wo ti pe ọmọ Ebonyi, nipinlẹ Ibo, lọkunrin naa to fi fẹ ẹ. Wọn ṣegbeyawo, wọn si bimọ obinrin kan.

Igbeyawo ọhun ti tuka bayii, Uhuo loun fẹẹ mu ọmọ oun lọ sabule lọdọ awọn obi oun l’Ebonyi, ṣugbọn Kemi ni ko sohun to jọ ọ, ni wọn ba ko ara wọn wa si kootu Ake l’Ọjọruu to kọja yii, wọn ni ki kootu ba awọn da si i.

Nigba to n ṣalaye fun kootu naa, Kẹmi to pe ẹjọ sọ pe oun paapaa ko de ilu awọn ọkọ oun atijọ naa ri nigba toun wa nile ẹ, ko mu oun debẹ ri boun ṣe ba a sọ ọ to, bi yoo ṣe waa gbe ọmọ oun ti ko ju ọmọ ọdun meje lọ sibẹ bayii loun ko mọ, ohun to jẹ koun wa si kootu niyẹn.

Kẹmi sọ pe ti Uhuo ba gbe ọmọ naa lọ sabule wọn, ko daju pe oun yoo ri i mọ, nitori ọlude lasan lo mu ọmọ naa sọdọ lati lo lọdun to kọja, to jẹ niṣe lo da a duro sọdọ ẹ ti ko jẹ ko pada sọdọ awọn obi oun to n gbe mọ, afigba ti wọn fọlọpaa mu un.

O ni ṣe ilẹ Ibo toun ko waa mọ loun yoo maa wa ọmọ lọ nigba ti Uhuo ba gbe e lọ sibẹ. Yatọ si eyi, obinrin naa ni giri maa n gbe ọmọ naa ṣere ni, ti yoo gan pẹẹli lojiji, to jẹ oun yoo maa sare kiri ni. To ba di pe o gbe e lọ silẹ Ibo bayii, bawo loju oun yoo ṣe to o. Nitori naa, ki kootu tete ba oun kilọ fun un, ko jawọ ninu erokero to n ro naa, oun ko le fi ọmọ oun silẹ fun un o.

Ninu ọrọ Uhuo Elias, o ni nigba toun fẹ Kẹmi, nnkan daa foun, awọn n jẹun lai si wahala. Ṣugbọn asiko diẹ lẹyin igbeyawo naa ni nnkan bẹrẹ si i nira, to jẹ ati-jẹun paapapa di ijangbọn. O ni igba yẹn ni Kẹmi kọ oun silẹ, oun si dupẹ bayii, oun ti fẹ ẹlomi-in.

Nipa ti ọmọ, ọkunrin naa sọ pe iya ati baba oun ṣi wa labule, awọn loun fẹẹ lọọ gbe ọmọ oun fun ki wọn maa tọju ẹ, ki i ṣe pe oun fẹẹ mu un lọ sile oun lọdọ iyawo keji toun fẹ.

O ni aya ọlẹ ni wọn n gba, wọn ki i ṣaa gba ọmọ ọlẹ. Boun ko ba fẹ iya ọmọ naa mọ, oun fẹẹ gba ọmọ oun. Wọn yoo ba oun tọju ẹ labule, giri to n ṣe e yoo si lọ.

Adajọ A.O Abimbọla lo gbọ ẹjọ naa, o ni ko ṣee ṣe lati fi ọmọ ọdun meje silẹ fun baba ẹ, ọmọ ọhun tun waa jẹ obinrin. Adajọ sọ pe ilu ti iya ọmọ ko de ri, ti Uhuo loun fẹẹ gbe ọmọ naa lọ sibẹ yoo ṣoro diẹ.

O ni Kẹmi ko ṣaa le maa tẹle e lọ siluu wọn nisinyii ti ko fẹ ẹ mọ, fun idi eyi, Adajọ sọ pe ọrọ wọn naa gba suuru, wọn yoo ni lati pada wa si kootu logunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun 2020 fun itẹsiwaju.

Leave a Reply