Tọkọ-tiyawo ku ninu ijamba mọto ni marosẹ Benin si Ijẹbu-Ode

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Titi dasiko yii lawọn eeyan ṣi n wararo lagbegbe Ajebandele, loju ọna marosẹ to lọ si Benin-Ọrẹ, lati Ijẹbu-Ode, nitori ibẹ ni ijamba mọto kan ti ṣẹlẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, to ṣe bẹẹ pa tọkọ-tiyawo, ti dẹreba wọn naa si tun dero ọrun.

Aago mẹwaa aarọ ku iṣẹju mẹẹẹdọgbọn ni ijamba yii waye gẹgẹ bi awọn TRACE to n ri si igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Ogun ṣe sọ.

Babatunde Akinbiyi ti i ṣe Alukoro TRACE, ṣalaye pe mọto akẹru kan lo kuro loju ọna ẹ, to lọ n gba ibi ti ko yẹ ko gba. O ni nigba naa lo lọọ kọ lu mọto ayọkẹlẹ Camry ti tọkọ-tiyawo yii wa ninu ẹ, ti dẹrẹba wọn  n wa wọn lọ.

Bi mọto akẹru to ni nọmba KTU 923 AJ naa ṣe kọ lu Camry to ni nọmba APP 477 DY ni tọkọ-tiyawo ọhun pade iku ojiji, dẹrẹba wọn nikan ni ko ku loju-ẹsẹ, wọn gbe oun deleewosan ṣugbọn o pada dagbere faye nibẹ naa ni.

Yatọ sawọn mẹta ti wọn ku yii, eeyan meji mi-in tun fara pa ninu ijamba yii bawọn TRACE ṣe wi.

Akinbiyi fi kun alaye ẹ pe ode inawo kan lawọn tọkọ-tiyawo naa ti n bọ, niluu Ọwọ, nipinlẹ Ondo. Eko lo ni wọn n pada si ti wọn fi kagbako iku ojiji lọwọ mọto akẹru to fi ọna tirẹ silẹ, to kọju si tiwọn.

Ileewosan J6 ni wọn gbe awọn to fara ṣeṣe lọ, wọn si gbe awọn oku lọ si mọṣuari ọsibitu Jẹnẹra Ijẹbu-Ode.

Leave a Reply