Tọkọ-tiyawo ta ọmọ oṣu kan lẹgbẹrun lọna aadọta naira l’Ode-Rẹmọ

 Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

  Tọkọ-taya lawọn eeyan meji yii, orukọ ọkọ ni Eze Onyebuchi, iyawo ni Oluchi Eze. Niṣe ni wọn gbe ọmọ wọn ti ko ju ọmọ oṣu kan lọ ta lẹgbẹrun lọna aadọta naira( 50,000) naira fun obinrin kan.

Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kejila yii, lọwọ ọlọpaa tẹ awọn mejeeji, iyẹn lẹyin ti olobo ta wọn pe Onyebuchi ati iyawo ẹ ti gbe ọmọ ikoko ti wọn ṣẹṣẹ bi ta. Eyi lawọn ọlọpaa Ode-Rẹmọ ṣe lọ sile wọn to wa l’Opopona Ayegbami, Ilara, l’Ode-Rẹmọ.

Nigba ti wọn n ṣalaye ohun to ṣẹlẹ, tọkọ-taya Eze sọ pe obinrin kan torukọ ẹ n jẹ Ruth Ọbajimi lo ran ẹni to ra ọmọ naa lọwọ awọn sawọn.

Wọn ni obinrin naa wa sile awọn lọjọ kẹrinla, oṣu Disẹmba yii, o si ni lati ọdọ awọn ajọ to n ri si ẹtọ ọmọniyan loun ti wa. Wọn lo sọ fawọn pe oun yoo bawọn tọju ikoko naa, oun yoo jẹ bii alagbatọ fun un, n lawọn ba gbe ọmọ awọn le e lọwọ, o si ko ẹgbẹrun lọna aadọta naira fawọn nigba to n lọ.

Alọ obinrin ti wọn ko mọ ri naa ni wọn ri lẹyin to gba ọmọ lọwọ wọn, ko sẹni to gburoo ẹ mọ lati ọjọ naa, o ti sa lọ tefetefe.

Iwa aibikita lori ọmọ tawọn tọkọ-taya Eze yii hu lo gbe wọn de akolo ọlọpaa, wọn si ti gbe wọn lọ sẹka to n ri si ṣiṣẹ ọmọ niṣekuṣẹ ati ijinigbe. Bakan naa ni ọga ọlọpaa Ogun ti paṣẹ pe ki wọn wa obinrin to waa ra ọmọ naa lawaari, koun naa le waa jiya rẹ labẹ ofin bo ṣe yẹ.

 

Leave a Reply