Tọkọ-tiyawo ti wọn ge ori oku niluu Ifọn ti foju bale-ẹjọ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lori ẹsun pe wọn ge ori ati ọwọ oku, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti wọ awọn tọkọ-taya kan, Ashifat Okunade ati Ashifat Mariam, lọ si kootu.

Nigba ti awọn tọkọ-taya naa fara han nile-ẹjọ ninu oṣu kẹta, ọdun yii, ọtọ ni ẹsun ti awọn ọlọpaa fi kan wọn, ṣugbọn nigba ti wọn pada wa lopin ọsẹ to kọja, agbefọba yi ẹsun wọn pada si igbimọ-pọ lati huwa buburu ati hihuwa aitọ si oku.

Agbefọba, John Idoko, sọ fun kootu pe laago kan ọsan ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹta, ọdun yii, ni ọwọ tẹ awọn olujẹjọ lagbegbe Dagbolu, niluu Ifọn, nipinlẹ Ọṣun, lasiko ti wọn ge ori ati ọwọ oloogbe kan, Rasheed Tiamiyu.

Nigba naa lọhun-un, adajọ fun awọn mejeeji ni beeli, nigba ti awọn ọlọpaa si tun fi ẹsun mi-in kan wọn bayii, wọn ni awọn ko jẹbi. Agbẹjọro wọn, Yẹmisi Akintajuwa, bẹ adajọ lati fun wọn ni beeli.

Onidaajọ Oluṣẹgun Ayilara ni ki awọn olujẹjọ maa jẹgbadun beeli ti wọn n lo lọ, o si sun igbẹjọ wọn si ọjọ kẹjọ, oṣu kin-in-ni, ọdun to n bọ.

Leave a Reply