Tọmiwa ati Jerry fibọn gba goolu lọwọ Mọla l’Ogijo

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 Jerry Chukwudi; ẹni ọdun mẹtalelogun, ati Tọmiwa Ọlawale; ẹni ọdun mejilelogun, lẹ n wo pẹlu ṣẹkẹṣẹkẹ lọwọ yii, awọn ọlọpaa lo ko o si wọn lọwọ lẹyin tọwọ ba wọn pe wọn fibọn gba goolu ọrun ati oruka ti iye rẹ jẹ miliọnu mẹfa naira lọwọ Hausa kan l’Ogijo.

Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun 2021, lọwọ tẹ awọn mejeeji yii, lẹyin ti Mọla ti wọn gba goolu lọwọ ẹ, Abubakar Hassan, lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Ogijo, pe ẹgbọn oun lo ni koun waa ko awọn goolu naa fun onibaara rẹ kan lagbegbe Igbo Olomu, n’Iṣawọ.

Abubakar sọ fawọn ọlọpaa pe lati Idi-Araba, ni Muṣin, loun ti wa si Iṣawọ, boun ṣi ṣe debẹ loun ri kọsitọma to ti n duro de oun naa.

O ni ọkunrin naa gbe oun sori ọkada, awọn jọ lọ sibi kan to da paroparo. O fi kun alaye ẹ pe nigba tawọn debẹ, oun ba awọn ọkunrin mẹta mi-in nibẹ, wọn yọ ibọn soun, wọn si tun fẹrẹ lu oun pa, bi wọn ṣe gba awọn goolu naa lọwọ oun niyẹn.

Ifisun rẹ yii lo jẹ kawọn ọlọpaa Ogijo tẹle e lọ sibẹ, wọn si wa gbogbo agbegbe naa titi tọwọ fi ba Tọmiwa ati Jerry yii, nigba ti awọn yooku wọn sa lọ.

Oruka goolu mẹta to le ni miliọnu mẹta naira ni wọn ri gba lọwọ awọn meji yii, bẹẹ ni wọn ṣi n wa awọn yooku to sa lọ pẹlu awọn goolu yooku gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe sọ.

Leave a Reply