Tọmọde-tagba lo n ṣedaro Dapọ Williams, ọmọ Yoruba daadaa to ku si London

Ilu oyinbo nibẹ lo n gbe, ni London. Ṣugbọn ki i ṣe pe o n gbebẹ bii isansa tabi bii alarinkiri lasan, lara awọn ọmọ Yoruba, lara awọn eeyan diẹ lati Naijiria, ti ọba ilu oyinbo, Queen Elzabeth, paapaa mọ pe o n gbebẹ ni. Idi ni pe ọrẹ wọn ni ni aafin ọba ilu oyinbo yii, nibi ti ọkunrin ti wọn n pe ni Dapọ Williams yii gbajumọ de niyẹn.

Ki eeyan kan too le da ileepo silẹ laarin gbungbun ilu London, to si ni opọlọpọ ileeṣẹ kaakiri orilẹ-ede awọn alawọ-funfun naa, yoo ti daju pe iru ẹni bẹẹ ki i ṣe eeyan yẹpẹrẹ. Ni tootọ si ni, Dapọ Williams ki i ṣe eeyan yepẹrẹ, tabi eeyan kan ṣaa, ohun to jẹ ki iku rẹ ka gbogbo aye lara ree, ati oyinbo ati eeyan dudu, ni London, ati lawọn ilẹ Afrika mi-in, ni wọn fẹẹ mọ ohun to pa ọmọ Yoruba pataki yii, ohun ti gbogbo wọn si kọkọ ro ni pe Korona to n paayan kiri yii lo tun mu oun naa lọ.

Ṣugbọn Korona kọ lo pa a, nitori ko ṣaisan tẹlẹ, o kan jade nile ko pada de mọ ni. O dagbere fawọn araale pe oun n lọ si ibi ile kan ti oun ṣẹṣẹ ra lati tun kọ, ki oun si tun gba ibẹ de ibi kan si ikeji, bo ṣe jade ti ko pada de ree titi ti ilẹ fi ṣu. Nigba ti iyawo rẹ wa a titi ti ko ri i, o sare sọ fawọn ọlọpaa, ṣugbọn gẹgẹ bii ofin, wọn ko le wa agbalagba to ba jade nile ti ko ba ti i pe wakati mẹrinlelogun, iyẹn odidi ọjọ kan gbako, ti wọn ko ti ri i. Nibẹ ni wọn ti duro, igba to si di wakati kẹrinlelogun loootọ, awọn ọlọpaa da si i, wọn bẹrẹ si i wa ọkunrin gbajumọ ilu London naa kiri. Wọn wa a titi ki wọn too kan mọto rẹ nibi kan lẹyin ọjọ keloo kan, ṣugbọn titi pa ni ilẹkun ibẹ naa wa, wọn ko si tun le deede ja ilẹkun ibẹ lai jẹ pe wọn gbaṣẹ, igba ti wọn yoo si fi ṣe eleyii tan, o ti di odidi ọjọ kẹfa ti wọn ti n wa Dapọ Williams.

Bi wọn ti ja ilẹkun naa ni wọn ba oku rẹ nibẹ loootọ, wọn ba a to ti ku sibẹ, to si fọwọ gba igbaaya rẹ mu sibẹ, eyi to n fi han pe lojiji ni ọkan rẹ da iṣẹ silẹ, nigba to si jẹ oun nikan lo lọ sibẹ lati ṣe ayẹwo ile to ṣẹṣẹ ra naa, ko sẹni kan nitosi lati sare gbe e lọ si ọsibitu nigba ti kinni naa mu un, bẹẹ ni ko si le da gbe ara rẹ sita, ohun to jẹ ki ọrọ naa ja si iku niyẹn.

Ohun to ya awọn eeyan lẹnu ninu ọrọ iku yii ni pe ki i ṣe oni, ki i ṣe ana, to ti maa n lọ sibi awọn ile tuntun to ba ṣẹṣẹ ra, nigba to jẹ lara awọn iṣẹ rẹ ni. Iṣẹ awọn ayaworan-ile lo fi bẹrẹ, ohun to si kọ jade nileewe Yaba College of Technology ree, ko too di pe o waa ka awọn iwe mi-in nipa bi wọn ṣe n wa epo bẹntiroolu, ati bi wọn ṣe n sọ epo naa di tita fun gbogbo aye. Aṣitẹẹti lọpọ eeyan mọ Dapo Williams si, aimọye ile lo si wa ni ikawọ ẹ ni London nibẹ, to jẹ oun lo ni wọn.

Ati pe ọpọlọpọ awọn ti iru nnkan bayii ba ṣe ni London, Dapọ Williams ki i jinna si wọn lati gba wọn, bi o ba si jẹ owo nina ni, yoo ti na owo naa tan ko too sọ fẹni kan. Nigba  to waa ṣẹlẹ si i ni ko seeyan ti yoo gba a nitosi yii, ohun ti iku rẹ ṣe jẹ ẹdun ọkan fun awọn ti wọn mọ ọn daadaa niyi. Bẹẹ bo ba ṣe ni aarin London ni, ko si ibi ti wọn ko ti mọ ọn, paapaa laarin awọn gbajumọ ti wọn ba n ṣe awọn ohun to bofin mu ni ilu ti wọn wa yii.

Boya ni ẹgbẹ gidi kan wa ti yoo jẹ ẹgbẹ awọn ọmọ Naijiria ti Dapọ Williams ko ni i jẹ ọkan ninu awọn aṣaaju wọn, tabi ko jẹ oun ni aṣaaju patapata. Agaga bi ẹgbẹ naa ba waa jẹ ti ọmọ Yoruba, tabi to jẹ eyi to n gbe aṣa ati iṣe Yoruba ga, iwaju bayii lẹ oo ti ba a. Ohun to si maa n sọ fawọn eeyan ni pe gbogbo ohun to ba jẹ mọ ti idagbasoke ilẹ Yoruba, ki wọn ma ṣe alai pe oun si i.

Ohun to sọ ọ di gbajumọ laarin awọn ọmọ Yoruba niyi, ti ọrọ naa si kan awọn ọmọ Naijiria lapapọ. Bo jẹ ọrọ oṣelu ti yoo mu idagbasoke ba ilẹ Yoruba, bo jẹ ọrọ awọn oṣere ti wọn n wa bi wọn yoo ṣe ri ibi ba wọle tabi dide ni ilu oyinbo, bo jẹ iṣẹ kan ti awọn ọmọ Yoruba ba fẹẹ ṣe nibẹ, bi wọn ba ti pe Dapo Williams, tabi to jẹ funra rẹ lo gbọ to da awọn ti ọrọ kan duro, latigba naa naa ni  yoo ti sọ kinni naa di ti ara rẹ, ti yoo si nawo-nara lati ri i pe kinni naa ṣee ṣe, o si mu anfaani gidi wa fẹni to ni in. Ko ti i pe ọdun kan bayii to ba awọn ọmọ Yoruba kan pe, nigba ti wọn da ẹgbẹ iranti orin Sikiru Ayinde Barisiter silẹ, ti wọn si ṣe eto ayẹyẹ naa ni London, ti wọn pe gbogbo eeyan lati waa sọ iru ẹni ti Barrister jẹ, ati bi orin rẹ yoo ti di ohun ti yoo tubọ kari aye si i, koda lẹyin to ti ku tan.

Awọn ti wọn gbe eto naa kalẹ royin owo ti Dapo Williams na, ati ipa ribiribi to ko, lati ri i pe eto naa ṣee ṣe, bẹẹ nigba to n sọrọ nibẹ, o ni ki i ṣe pe oun fi taratara fẹran orin Fuji ọhun, ṣugbọn ohun to le gbe aṣa ati iṣe Yoruba ga, ti yoo si ṣe anfaani fun awọn ọmọ Yoruba to ba n ṣe e loun fẹẹ maa da si ni. Nigba ti awọn Buhari n mura lati gba ijọba, ti gbogbo aye si gba wọn gbọ pe ayipada gidi ni wọn yoo mu ba Naijiria, ọkan ninu awọn to sare kiri laarin awọn ọmọ Naijiria fun atilẹyin Buhari ni Dapo Williams, nigba to si wọle tan naa, ọkan ninu awọn ti Buhari kọkọ de ọdọ rẹ niluu oyinbo yii naa ni.

Ohun ni awọn elẹgbẹ rẹ ṣe sọ o di ko-si-lajọ-ajọ-o-kun, nitori wọn ni eeyan kan ṣoṣo bii mẹẹẹdọgbọn ni. Ohun to si ṣe ri bẹẹ naa ni pe Ọlọrun fun un lowo, o fun un ni ifẹ si awọn eeyan rẹ, o si fẹ idagbasoke ibi ti wọn ti bi i.

Ọpọ eeyan ni iru eleyii yoo wu lati ṣe, ti wọn yoo fẹ lati da oriṣiiriṣii ara bi wọn ba de ilu oyinbo, ṣugbọn igbesẹ akọkọ ti wọn gbọdọ gbe ni lati ba ọna to ba dara wọ ilu oyinbo yoowu ti wọn ba fẹẹ wọ, eleyii ni yoo jẹ ki wọn le ni iṣẹ to dara lọwọ, ti wọn yoo si le maa ṣe ohun gbogbo lọna to ba ofin mu. Lati ọdun 1999 ni Dapọ Williams ti mọ Ọbabinrin Elizabeth, ti iyẹn naa si mọ ọn, to jẹ gbogbo ohun ti wọn ba fẹẹ ṣe ni aafin wọn ni wọn yoo pe e si gẹgẹ bii ọkan ninu awọn alejo to ṣee fọkan tan niluu wọn. Ko sohun to fa a ju pe wọn mọ pe ki i ṣe isansa lọ: ko ba ẹburu wọlu wọn, ko si mura lati lu wọn ni jibiti, o lọ sibẹ lati ṣiṣẹ aje ni ọna to ba ofin mu ni.

Ki Ọlọrun tẹ Dapọ Williams si afẹfẹ rere o, ki gbogbo ẹni to ba si n mura ilu oyinbo fi ọrọ ọkunrin ọmọ Yoruba pataki yii ṣe awokọṣe, pe o le dara fawọn naa ni ilu oyinbo, bi awọn ba ti ba ọna to dara de ọhun, ti awọn si ṣe ohun gbogbo lọna to ba ofin mu.

 

Leave a Reply