Toogun si ge Mọdinat si wẹwẹ bii ẹran ewurẹ, oogun owo lo fẹẹ fi i ṣe n’Ileogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọkunrin afurasi apaniṣowo kan, Toogun, ti wa lakolo ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun bayii lori ẹsun pe o pa iyaale ile kan, Salmon Asiata.
Gẹgẹ bi Alakooso ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun, Amitolu Shittu, ṣe sọ, ọkan lara awọn ọmọ obinrin yii lo lọọ fi ọrọ naa to awọn Amọtẹkun agbegbe Ileogbo, nijọba ibilẹ Ayedire leti.
Ọmọ yii ṣalaye fawọn Amọtẹkun pe iya oun wọnu ile Toogun, ti ko si jade pada mọ. O lo ti pe ọsẹ mẹrin bayii ti wọn ti n wa obinrin naa kaakiri.
Bi awọn Amọtẹkun ṣe gbọ ni wọn bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa, wọn lọ si agbegbe Oke-Ọṣun ti ọkunrin afurasi yii n gbe, ṣugbọn wọn ko ba a nile.
Amitolu ṣalaye pe awọn kọkọ fi pampẹ ofin gbe meji lara awọn mọlẹbi Toogun, ṣugbọn awọn tun fi wọn silẹ nitori awọn kọ ni wọn ṣẹ, amọ wọn ṣeleri lati ran awọn lọwọ lori bi ọwọ yoo ṣe tẹ afurasi naa.
Lẹyin ọpọlọpọ iwadii, pẹlu ifọwọsowọpọ agbofinro yooku, ọwọ tẹ Toogun lagbegbe Lalupọn, nijọba ibilẹ Lagelu, nipinlẹ Ọyọ.
Nigba ti afurasi yii jẹwọ lo mu awọn agbofinro lọ sibi to sin oku obinrin naa si, nigba ti wọn hu u jade, lekiri-lekiri ni wọn ge ẹya-ara rẹ sibẹ.
Latigba naa ni Toogun ti wa lakolo awọn ọlọpaa fun iwadii.

Leave a Reply