Faith Adebọla
Latari awuyewuye to waye lọsẹ to kọja lori ọrọ abuku to sọ nipa orin ‘Oniduuro Mi’ eyi ti onkọrin ẹmi nni, Adeyinka Adesioye, tawọn eeyan mọ si Alaṣeyọri kọ, gbajugbaju olorin ẹmi nni, Tọpẹ Alabi ti gboṣuba fawọn ololufẹ rẹ, o dupẹ lọwọ wọn, lẹyin to ti kọkọ tọrọ aforiji nipa iṣẹlẹ ọhun.
Ori ikanni instagiraamu rẹ ni Tọpẹ ti lọọ kọ ọrọ ranṣẹ sawọn ololufẹ rẹ lọjọ Satide yii, akọle to fun ọrọ ọhun ni: Idupẹ mi si gbogbo eeyan, o si kọ ọrọ sibẹ pe “Mo fi tọkantọkan dupẹ lọwọ gbogbo yin o, fun bẹ ẹ ṣe duro ti mi laarin ọsẹ kan yii. Ọlọrun Ọba ko ni i fi ẹyin naa ṣilẹ lae, lorukọ Jesu. Mo dupẹ gidigidi lọwọ yin o, mo si gbadura pe ki Ọlọrun bukun fun yin lorukọ Jesu.”
Bayii ni Tọpẹ ṣe mọ riri awọn ololufẹ rẹ, fun atilẹyin wọn lasiko ti awuyewuye n ja ranyin lori orin “Oniduuro Mi” to fẹnu abuku kan.
Ṣaaju ni Tọpẹ Alabi ti kọkọ fi atẹjade kan lede nibi to ti loun tuuba, oun tọrọ aforiji lori iṣẹlẹ naa.