Tori arun Korona to tun n yọju, Sanwo-Olu ni kawọn ileejọsin ati ibi ariya din ero ku

Faith Adebọla, Eko

Yoruba bọ, wọn ni ifura loogun agba, ijọba ipinlẹ Eko ni toju tiyẹ l’aparo awọn fi n riran lori arun Korona to pawọda bii ọga kari aye yii, tori naa, wọn ti paṣẹ pe kawọn ileejọsin, awọn ibi ariya, ile ọti ati awọn gbọngan ayẹyẹ eyikeyii nipinlẹ naa bẹrẹ si i din ero to maa lo ibẹ ku si idaji iye to yẹ ko jẹ bayii.

Sanwo-Olu sọrọ yii nirọlẹ ọjọ Aiku, Sannde yii, nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ nile ijọba ipinlẹ Eko, eyi to wa lagbege Marina, l’Erekuṣu Eko, lọhun-un.

Gomina ni lati ipari oṣu kẹta lawọn ti ṣakiyesi pe akoran arun Koronafairọọsi ẹlẹẹkeji ti n kogba sile, iye eeyan ti ayẹwo n gbe jade pe wọn ti lugbadi arun naa si ti dinku jọjọ.

O ni ko dun mọ oun ninu pe pẹlu bijọba oun ṣe n sapa to lati gba arun naa wọlẹ patapata, niṣe ni Korona ẹlẹẹkẹta tun gbori wọle, kaka ki ewe agbọn rẹ si dẹ, niṣe lo n le koko si i.

Gomina naa ni laarin ọjọ kẹjọ, oṣu karun-un, si ọjọ kẹjọ, oṣu keje, ta a wa yii, awọn arinrin-ajo to le ẹgbẹrun lọna aadọta (50,322), ni wọn gba papakọ ofurufu Muritala Mohammed to wa n’Ikẹja wọle s’Ekoo, ati pe ko rọrun lati tọpasẹ wọn fun ayẹwo latari bi awọn nọmba tẹlifoonu ti wọn fi silẹ tabi adirẹsi ti wọn lawọn n lọ ki i tọna. O ni ewu gidi lawọn ero wọnyi jẹ fun olugbe Eko ati ọmọ Naijiria bi wọn ba lọọ ṣe akoran arun aṣekupani ọhun kaakiri.

Latari eyi, Sanwo-Olu sọ pe o ti di dandan wayi pe kawọn arinrin-ajo pese adirẹsi ati nọmba foonu to gbeṣẹ kawọn baa le maa ṣakiyesi wọn. “Ẹnikẹni to ba kuna lati pese awọn nnkan wọnyi, tabi ti ohun to pese jẹ irọ, tọhun yoo foju wina ofin.”

Lara awọn ijiya to wa fawọn ajeji to ba kọti ọgbọyin sikilọ yii ni ki wọn padanu aṣẹ igbeluu, tabi kijọba fi wọn sọko pada sibi ti wọn ti n bọ lẹyẹ-o-sọka, bo ba si jẹ ọmọ oniluu ni, tọhun yoo fimu kata ofin to wa lori arun Korona.

Bakan naa lo ni kawọn agbofinro bẹrẹ si i ṣọ awọn ileejọsin atawọn gbọngan ariya, ile ijo atawọn ile tero n pọ si lati ri i pe wọn pa aṣẹ yii mọ.

Leave a Reply