Tori awọn OPC mẹta ti wọn ju sẹwọn, awọn ọdọ Ibarapa ṣewọde lọ sọfiisi Makinde n’Ibadan

Faith Adebọla

Titi di asiko ti a fi n ko iroyin yii jọ ni awọn ọdọ ilẹ Ibarapa, lagbegbe Oke-Ogun, nipinlẹ Ọyọ, fi taku sẹnu geeti to wọ ọfiisi Gomina Ṣeyi Makinde tipinlẹ Ọyọ, to wa ni Agodi, Ibadan, awọn ọdọ naa n ṣewọde ta ko bijọba ati ile-ẹjọ ṣe ti awọn ọmọ ẹgbẹ OPC mẹta kan mọ ọgba ẹwọn, wọn lawọn fun ijọba lọsẹ meji pere lati ṣe ohun tawọn n fẹ.

Nnkan bii aago mẹwaa aabọ owurọ ọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii, ni awọn ọkọ to gbe awọn ọdọ naa wa lati ilu Igangan, Eruwa, Lanlatẹ, Ayetẹ, Idere, Tapa ati Igbo-Ọra ja wọn silẹ niwaju ọfiisi gomina naa, oju-ẹsẹ si lawọn ọdọ naa ti n kọrin oriṣiiriṣii lati fi ẹdun ọkan wọn han.

Oniruuru akọle ni wọn gbe dani, diẹ lara awọn akọle naa ka pe ‘Ẹ ba wa tu awọn ọmọ OPC mẹta silẹ lahaamọ o,’ ‘Awa o fẹ awọn apaayan darandaran mọ niluu wa,’ ‘Ibarapa ki i ṣe ilẹ maaluu, iṣẹ ọgbin la n ṣe nibẹ,’ ‘Awa o fara mọ fifi maaluu jẹko ni gbangba n’Ibarapa o,’ ati ‘Wakili lọdaran, ki i ṣe awọn to mu un’.

Ẹgbẹ awọn ọdọ kan niluu Igangan, Igangan Development Advocates, eyi ti Ọgbẹni Ọladiran Ọladokun ṣe kokaari rẹ lo ṣagbatẹru ifẹhonu han naa.

Akọwe ẹgbẹ naa, Abedeen Oguntowo, to ba ALAROYE sọrọ lori aago lọjọ Aje sọ pe “Iwọde alaafia la ṣi ba wa, a o ba tija wa, a si ti jẹ kijọba mọ ohun ta a fẹ.

“Olori awọn oṣiṣẹ ọba lọfiisi gomina (Ọgbẹni Bisi Ilaka) ni gomina ran waa ba wa sọrọ. Wọn ti ni ka mu suuru, ka fawọn laaye diẹ, awọn maa ṣe ohun ta a beere fun. Wọn ni bo ṣe jẹ pe ipinlẹ Ọyọ ni nnkan ti ṣẹlẹ, ipinlẹ Ọyọ ni ile-ẹjọ wa, ipinlẹ Ọyọ naa ni wọn ti awọn ọmọ OPC mọ, dajudaju ijọba ipinlẹ Ọyọ maa ṣiṣẹ lori ẹ.”

Oguntọwọ ni o di irọlẹ kawọn too kuro nibi iwọde naa, ati pe awọn yoo fi ọsẹ meji silẹ fun ijọba ipinlẹ Ọyọ ki wọn ṣe ohun ti wọn lawọn maa ṣe si ọrọ to wa nilẹ yii, lẹyin ọsẹ meji, “a ti sọ fun gomina pe a maa pada wa, a kan fi eleyii fa ijọba leti ni.”

Yatọ si itusilẹ awọn ọmọ OPC to wa lahaamọ, awọn ohun mi-in ti wọn tun lawọn tori ẹ wa ni pe awọn o fẹẹ ri Fulani kankan mọ ninu igbo ati oko ilẹ Ibarapa, awọn o si ni i faaye gba fifi ẹran jẹko ni gbangba.

Oguntọwọ ni bo tilẹ jẹ pe Wakili ti wa lọdọ awọn agbofinro, awọn ọmọ rẹ ati isọngbe rẹ ṣi wa ninu igbo Abule Kajọla, ko si ti i ṣee ṣe fawọn agbẹ ati awọn obinrin to n raja oko lati ṣiṣẹ aje wọn nibẹ, tori ibẹru awọn Fulani apaayan wọnyi.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii, lawọn agbofinro foju awọn ọmọ OPC mẹta, Awodele Adedigba, Dauda Kazeem ati Hassan Ramọn, to lọọ mu Fulani darandaran Iskilu Wakili, bale-ẹjọ, kootu naa si paṣẹ fifi wọn sahaamọ ọgba ẹwọn Abolongo, nigba ti igbẹjọ yoo maa tẹsiwaju.

 

 

 

Leave a Reply