Tori bi wọn ṣe n ji awọn akẹkọọ gbe, ẹgbẹ olukọ lawọn maa ti ileewe pa

Faith Adebọla

 

 

 

Pẹlu bi iṣẹlẹ jiji awọn ọmọleewe ati olukọ gbe lapa Oke-Ọya orileede yii ṣe di lemọlemọ, ẹgbẹ awọn olukọ Naijiria (Nigeria Union of Teachers), ati ẹgbẹ awọn akẹkọọ (National Association of Nigerian Students), ti sọ pe awọn maa tilẹkun awọn ileewe pa jake-jado orileede yii ni. Ki i ṣe apa ariwa nikan o, tori ko si aabo to peye fawọn olukọ ati akẹkọọ kaakiri mọ bayii.

Oru mọju ọjọ Ẹti, Furaidee yii, lawọn agbebọn kan tun lọọ ji awọn ọmọọlewe akẹkọọ-binrin bii ọọdunrun (300) ko nigba ti wọn ṣi n sun lọwọ, ti wọn si ṣe bẹẹ ko wọn wọgbo lọ.

Nigba to n ba akọroyin wa sọrọ lori aago nipa iṣẹlẹ yii, Dokita Mike Ene, to jẹ akọ̀wé apapọ ẹgbẹ awọn olukọ nílẹ̀ wa, sọ pe o ti han gbangba bayii pe niṣe lawọn kan fẹ diidi fawọ aago itẹsiwaju eto-ẹkọ lorileede yii sẹyin, tabi ki wọn tiẹ doju ẹ de paapaa.

“Awọn iṣẹlẹ ijinigbe to n waye lọtun-un losi maa mu kawọn eeyan kaaarẹ ọkan nipa eto ẹkọ, o si maa le awọn kan sa nileewe, wọn aa di alaabọ ẹkọ, wọn o ni i fẹ lati tẹsiwaju mọ. Awọn to ba si n tiraka lọ naa, inu ibẹrubojo ni wọn maa wa. Bawo leeyan ṣe le kawe kiwee naa wọri nibi to ti n wo fẹtofẹto pẹlu ipaya boya awọn ajinigbe le waa ya bo wọn?

“A ti ri i pe awọn ileewe to jẹ kidaa ọkunrin tabi obinrin ni wọn yan laayo lati maa ṣe akọlu si bayii, lati mu kawọn majeṣin wọnyẹn ni irẹwẹsi ọkan nipa ẹkọ wọn, wahala tawọn akẹkọọ ti wọn ji ni Kagara la ṣi n ba yi lọwọ ti eleyii fi tun ṣẹlẹ. Bọrọ ṣe ri yii, ko sigba ta o ni ti awọn ileewe pa patapata, tori ko si aabo fawọn akẹkọọ ati olukọ.

A ti ni kijọba ṣe fẹnsi sawọn ileewe ijọba gbogbo ki eto aabo ati aago idagiri si wa ni sẹpẹ, ṣugbọn wọn o ti i ṣe bẹẹ. A maa ṣepade lori ọrọ yii,” bẹẹ ni akọwe apapọ ẹgbẹ naa wi.

Ọgbẹni Ọlawale Samuẹl to jẹ oluṣekokaari ni Guusu/Iwọ-Oorun ẹgbẹ awọn akẹkọọ, NANS, ni tiẹ sọ pe saka lo daju bayii pe ijọba ti kuna patapata lati pese aabo fun ẹmi ati dukia awa ọmọ orileede yii.

“Awa akẹkọọ o nigbẹkẹle kan mọ ninu ijọba yii, ijọba naa ko sapa to, wọn o si ṣe ohun to yẹ lati dawọ eto aabo to dẹnu kọlẹ yii duro. Awọn olori ẹgbẹ awọn akẹkọọ, NANS maa ṣepade pajawiri lori ọrọ yii, a maa bẹrẹ iwọde kaakiri awọn ileewe, a si maa ri i pe a tilẹkun awọn ileewe pa, tori a o le jẹ kijọba sọ ẹmi awọn ewe ati ọdọ di nnkan iṣere lasan bii eyi.”

Leave a Reply