Tori bile-ẹjọ ṣe wọgi le isọri kẹrinlelọgọrin ofin eto idibo, awọn aṣofin pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun

Faith Adebọla

 Kaka kewe agbọn dẹ, niṣe lo n le koko si i lọrọ awuyewuye lori idajọ ile-ẹjọ to wọgi le ila kejila ni isọri kẹrinlelọgọrin ofin eto idibo ilẹ wa, iṣẹlẹ naa bi awọn aṣofin agba ati awọn ọmọ ileegbimọ aṣoju-ṣofin ninu, kaluku wọn lo fi aidunnu wọn han si aṣẹ ile-ẹjọ, ti wọn si fẹnuko lati pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lẹyẹ-o-ṣọka.

Ileegbimọ aṣofin mejeeji ṣe ipinnu yii lasiko ijokoo wọn to waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtalelogun, ọsu Kẹta yii, bo tilẹ jẹ pe lati ọjọ kejilelogun lawọn aṣofin agba, iyẹn awọn sẹnetọ ilẹ wa, ti tutọ soke, ti wọn si foju gba a, lori aṣẹ ile-ẹjọ naa.

Bo tilẹ jẹ pe Igbakeji aarẹ ile naa, Ovie Omo-Agege, lo dari ipade wọn lọjọ Tusidee, Sẹnetọ Thomson Sekibo lo nawọ soke lati pe akiyesi awọn ẹlẹgbẹ rẹ si aṣẹ ile-ẹjọ naa, o ni:

“Ọrọ yii ṣe pataki gidi o. Awọn ti wọn lọ ile-ejọ lati ta ko ofin yii, wọn o sọ fun wa, wọn o pe wa si i, awa ta a ṣofin niyi, wọn o tiẹ jẹ ka mọ pe ẹjọ kankan wa ni kootu. Ojiji la gbọ nipa idajọ, ẹsẹkẹsẹ si nijọba apapọ lawọn ti ṣiṣẹ lori ẹ. Iwa ti wọn hu yii lewu gidi, a si gbọdọ ṣepinnu pato nipa ẹ, apẹẹrẹ buruku ta o gbọdọ jẹ ko lọ bẹẹ ni, tori o tumọ si pe awọn ofin mi-in le di eyi tile-ẹjọ yoo maa wọgi le lọ wọgi le bọ lọjọ iwaju, yanpọnyanrin niru ẹ si maa da silẹ.”

Bo ṣe sọrọ yii tan lawọn ẹlẹgbẹ rẹ kin in lẹyin, ṣugbọn wọn fẹnu ko lati so ijiroro naa rọ di ọjọ keji, Wẹsidee, ti Olori awọn aṣofin, Sẹnetọ Ahmed Lawan, yoo wa nijokoo.

Lọjọ keji ti wọn jokoo, Sekibo ran awọn ẹlẹgbẹ rẹ ki wọn ma gbagbe ọrọ asọti wọn ana. Ọpọ awọn sẹnetọ to sọrọ nipa aṣẹ ile-ẹjọ naa ni wọn sọ pe aṣiloye patapata ni adajọ naa ṣe pẹlu bo ṣe tọka si awọn isọri kan ninu ofin ilẹ wa lati fi gbe aṣẹ rẹ lẹyin. Wọn lawọn oṣiṣẹ ọba ti wọn n ṣiṣẹ ounjẹ oojọ wọn lọrọ kan ninu isọri to tọka si, ki i ṣe awọn oṣiṣẹ tijọba yan sipo oṣelu bii minisita, kọmiṣanna, eyi ti ofin kẹrinlelọgọrin ti wọn n sọrọ nipa ẹ yii tọka si.

Ati pe eto idibo ninu ẹgbẹ oṣelu (congress), apero gbogbogboo (convention) tabi eto idibo lati yan ọmo-oye (primary) ni ofin kẹrinlelọgọrin yii n tọka si, nigba ti ofin ilẹ wa ti adajọ fa yọ n sọrọ nipa eto idibo lati yan awọn alakooso ilu bii gomina, aarẹ tabi awọn aṣofin, wọn lọrọ naa ko jọra wọn rara, ko si bara mu.

Lẹyin ijiroro wọn, wọn ni kawọn aṣofin dibo boya ki wọn pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lori ọrọ yii, aṣofin mọkanlelọgọrin lo dahun pe awọn fẹ bẹẹ, Lawan si lu u lontẹ.

Ipinnu tawọn aṣoju-ṣofin ṣe lori ọrọ yii lọjọ Wẹsidee tun lagbara ju tawọn sẹnetọ lọ, tori, yatọ si pipẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, wọn tun lawọn maa fẹjọ adajọ to paṣẹ pe ki wọn pa ofin kẹrinlelọgọrin yii rẹ sun lọdọ igbimọ to n ri si ọrọ awọn adajọ, National Judicial Council (NJC), wọn lawọn o nifẹẹ si aṣẹ to pa, wọn laṣẹkaṣẹ gbaa ni, ati pe bawo lo ṣe le pa aṣẹ ta ko ileegbimọ aṣofin bẹẹ, lai jẹ pe orukọ awọn wa lara olujẹjọ ninu ẹsun yii. Wọn lo jọ pe agbara n pa adajọ naa bii ọti, tabi iromi to n jo lori omi ni, boya onilu rẹ wa nisalẹ odo, awọn si fẹ ki NJC bawọn tan ina wo idi ẹjọ ati aṣẹ naa.

Olori awọn aṣoju-ṣofin naa, Fẹmi Gbajabiamila, paṣẹ pe ki Minisita feto idajọ nilẹ wa, Mallam Abubakar Malami, fi ofin idibo naa silẹ nigin-nigin bawọn ṣe ṣe e, ko ma si dan an wo lati loun n pa ila kejila, isọri kẹrindinlogoji, naa rẹ, titi ti ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun tawọn fẹẹ pe yoo fi pari, ti idajọ yoo si waye.

Gbajabiamila ni ileeṣẹ Aarẹ, tabi ẹnikẹni ti Aarẹ ba yan sipo ko lagbara labẹ ofin lati pa ami kọma lasan, bo ti wu ko kere to rẹ ninu ofin tawọn aṣofin ba ṣe, aṣilo agbara niyẹn tumọ si, gbigba ojuṣe awọn aṣofin ṣe ni wọn n pe’ru ẹ, awọn o si ni i fara mọ ọn.

Awọn aṣofin naa ni olupẹjọ ti wọn lo pẹjọ yii ko ṣalaye bi isọri ti wọn paṣẹ le lori ṣe kan an, boya ipalara kan wa ti ofin eto idibo naa ṣe fun un, ati idi to fi fẹ ki wọn yọ ọ kuro tabi pa a rẹ, ati pe, olupẹjọ yii ko si nipo oṣelu, ki i si i ṣe oṣiṣẹ ọba, ọrọ ti ko kan an lapa lẹsẹ lo gbale-ẹjọ lọ fun, awọn o si ni i gba iru aṣẹ bẹẹ.

Leave a Reply