Faith Adebọla
Lẹyin ti aago meje aṣaalẹ ba ti lu, gbogbo ẹni to ba n gbero lati wọ ilu Ṣagamu, nijọba ibilẹ Ṣagamu, nipinlẹ Ogun, tabi to n rin irin gberegbere lagbegbe naa, titi di aago mẹfa owurọ, afaimọ ni tọhun ko ni i pari irinajo rẹ si ẹyin kanta awọn ọlọpaa, tabi ahaamọ wọn, lati ṣalaye idi to fi lufin ọba.
Eyi ko ṣẹyin aṣẹ konilegbele tijọba ipinlẹ Ogun pa lori ilu Ṣagamu ati agbegbe rẹ lasiko yii, bẹrẹ lati ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, latari bawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ṣe gbe omi ija kana niluu ọhun, ti wọn si n fẹmi ara wọn ataraalu ṣofo bii omi ojo.
Akọwe iroyin si Gomina ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Lekan Adeniran, to fi ikede yii lede lọjọ Aje, Mọnde, ọhun lorukọ ọga rẹ, sọ pe:
“Eyi ni lati kede fawọn olugbe ilu Ṣagamu ati agbegbe rẹ pe ofin ti de lilọ bibọ awọn eeyan ati ọkọ lagbegbe yii, gẹgẹ bii apa kan igbesẹ tijọba gbe lati ṣakoso eto aabo ẹmi ati dukia.
“A rọ gbogbo ẹyin olugbe agbegbe yii lati pa ofin konilegbele yii mọ daadaa, kẹ ẹ si fọwọ sowọ pọ pẹlu awọn ẹṣọ eleto aabo gbogbo lati da alaafia ati aabo pada siluu, ati lati fọwọ ṣinkun ofin mu awọn adaluru arufin ti wọn fi iwa ọdaran ro ilu pọ, ki wọn le jiya ẹṣẹ wọn lẹyẹ-o-sọka.”
Ẹ o ranti pa niṣe lẹjẹ n ṣan bii omi niluu Ṣagamu pẹlu bawọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun ṣe n bara wọn ja, to si jọ pe wọn ti pinnu lati ba ara wọn na an tan bii owo lasiko yii, eeyan to ju ogun lọ ni wọn lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun da ẹmi ẹ legbodo laarin alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹsan-an yii, si afẹmọju ọjọ Aje, Mọnde, oṣu yii kan naa.
ALAROYE gbọ pe bii ẹni figbalẹ pa eṣinṣin lawọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun ‘Ẹiyẹ’ ati ‘Aye’ n wọle tọ ara wọn lọ, ti wọn si bẹrẹ si i fi ibọn, ada, aake ati awọn nnkan ija oloro ṣa ara wọn balẹ.
Nibi tọrọ naa buru de, bi wọn ba wa ẹlẹgbẹ okunkun kan lọ, ti wọn ko ba a, niṣe ni wọn n yinbọn pa ẹnikẹni ti wọn ba ba nibẹ, eyi ni wọn lo fa a ti wọn fi pa awọn ọmọleewe sẹkọndiri mẹta kan ti wọn lọọ gẹrun ni ṣọọbu onigbajamọ kan lagbegbe Sabo, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹsan-an yii.