Tori ijamba ina nla, ijọba ti biriiji Apọngbọn pa l’Ekoo, wọn le awọn ontaja danu

Faith Adebọla, Eko

Wakati mejidinlaaadọta pere nijọba ipinlẹ Eko fun gbogbo awọn to n taja tabi ti wọn gbe ile onipako labẹ biriiji Apọngbọn nisalẹ lati palẹ ẹru wọn mọ, ki wọn si kuro patapata ni gbogbo ayika naa, aijẹ bẹẹ, wọn yoo ri pipọn oju ijọba.

Bakan naa nijọba Eko paṣẹ titi afara naa pa, titi digba ti wọn ba ṣayẹwo, ti wọn si ṣatunṣe to yẹ si i. si i.

Oludamọran pataki si gomina Eko lori ọrọ agbegbe okoowo (CBD), Ọgbẹni Gbenga Oyerinde, lo kede aṣẹ ijọba naa latari ijamba ina ọmọ ọrara kan to ṣẹlẹ labẹ biriiji ọhun laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta yii, nibi ti ọgọọrọ dukia ti ṣofo, ti tawọn eeyan diẹ si fara pa.

Titi dasiko yii, ko ti i sẹni to le sọ pato ohun to ṣokunfa ijamba ina naa, ṣugbọn awọn kan lara awọn to n ṣe kara kata labẹ biriiji naa sọ pe afaimọ ko ma jẹ epo bẹntiroolu tawọn onimọto ati awọn onijẹnẹretọ n tọju pamọ sabẹ biriiji ọhun lo fa ọṣẹ nla yii.

Ọga agba fun ajọ LASEMA to n ri si iṣẹlẹ pajawiri l’Ekoo, Dokita Oluwafẹmi Oke-Ọsanyintolu, sọ pe “afara yii maa wa ni titi pa digba ti a ba ṣayẹwo si i, ta a si ni idaniloju pe o ṣi ṣee lo fawọn onimọto, tori iṣẹlẹ ina yii ṣọṣẹ gidi, a si gbọdọ mọ ipo ti biriiji naa wa, ki ẹmi awọn eeyan ma baa si ninu ewu.”

Bakan naa ni Oyerinde kilọ pe ọlọja, ontaja tabi olugbe eyikeyii tọwọ awọn agbofinro ba tẹ ni ayika biriiji ọhun lati ọjọ Abamẹta, Satide, ile-ẹjọ lawọn maa taari onitọhun si, wọn yoo si da sẹria gidi fun un.

O ni iwa aigbọran ati aibikita awọn to n ṣe kara-kata kaakiri awọn ọja nipinlẹ Eko ti pọ ju, pẹlu bi ijọba ṣe n parọwa fun wọn to, tawọn n ṣe ipade loorekoore pẹlu wọn, tawọn si n kilọ nipa oriṣiiriṣii ewu ti wọn gbọdọ sa fun, sibẹ, niṣe lọpọ ninu awọn eeyan naa n kọti ikun, ti wọn si n dẹjaa pẹlu awọn nnkan to le fa ijamba.

O gboṣuba fawọn oṣiṣẹ panapana ati awọn ajọ adoola ẹmi, awọn oṣiṣẹ to n ri si ọrọ pajawiri, o ni gbogbo wọn ni wọn fọwọsowọpọ lati pa ina buruku naa, eyi si ni ko jẹ kẹnikẹni padanu ẹmi, tabi ki ina naa jo ajoran, tori awọn ile pako ati isọ itaja rẹpẹtẹ lo wa layiika naa, bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan diẹ fara pa lasiko akọlukọgba to waye nigba tawọn eeyan n sa asala fẹmi wọn.

Leave a Reply