Tori iwọde lori iku Deborah, ijọba paṣẹ konile-gbele ni Ṣokoto

Faith Adebọla

Ijọba ipinlẹ Sokoto ti kede ofin konile-gbele fun wakati mẹrinlelogun nigboro ilu Sokoto, latari iwọde to n lọ lọwọ niluu naa, ati akọlu to n waye lori iku akẹkọọ-binrin Deborah Yakubu Samuel, tawọn akẹkọọ ẹlẹgbẹ rẹ kan pa nifọnna-ifọnṣu l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejila, oṣu Karun-un yii.
Gomina ipinlẹ Sokoto, Aminu Waziri Tambuwal, lo paṣẹ konile-gbele naa ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Satide yii, o ni igbesẹ naa pọn dandan lati dẹrọ akọlu, ifẹmiṣofo ati biba dukia jẹ, eyi tawọn janduku kan ti gun le nigboro ilu Sokoto bayii.
Ba a ṣe gbọ, awọn agbaweremẹsin kan ni wọn bẹrẹ iwọde laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide yii, wọn ni inu awọn ko dun si bawọn ọlọpaa ṣe mu meji ninu awọn afurasi ti wọn lọwọ ninu ṣiṣekupa Deborah, wọn ni kijọba fi awọn ti wọn mu silẹ, awọn ko ri aburu kan ninu akọlu ati iku oro ti wọn fi pa oloogbe naa.
Awọn agbaweremẹsin naa ti bẹrẹ si i sun taya kaakiri igboro Sokoto, bẹẹ la gbọ pe wọn ti lọọ dana sun ṣọọṣi Katoliiki kan to wa niluu naa, bẹẹ ni wọn n ba awọn dukia jẹ, wọn tun gbiyanju lati ṣakọlu sawọn ọlọpaa ni teṣan wọn. Wọn ni ibọn ọlọpaa ba ọkan lara awọn oluṣewọde ọhun.
Ninu awọn fidio tawọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ju sori ẹrọ ayelujara, a ri ọkan lara awọn oluwọde naa tibọn ba, wọn si ṣafihan awọn oluwọde tinu n bi ọhun bi wọn ṣe n ba awọn dukia jẹ, ti wọn si n sun taya kaakiri oju popo.
Tẹ o ba gbagbe, lọsẹ to pari yii ni awọn akẹkọọ kan kọ lu akẹkọọ-binrin naa, ti wọn si lu u pa, lẹyin ti wọn pa a tan ni wọn tun dana sun oku rẹ. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o sọrọ odi si Anabi Muhammed.

Leave a Reply