Faith Adebọla, Eko
Titi pa ni gbogbo ọja yoo wa l’Ekoo lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii latari eto adura pataki to maa waye ni iranti ọjọ kẹjọ ti gomina ipinlẹ Eko nigba kan, Oloye Lateef Kayọde Jakande jade laye.
Iyalọja agba fun gbogbo ipinlẹ Eko, Abilekọ Fọlaṣade Tinubu-Ojo, lo kede eyi l’Ọjọbọ, Tọsidee, o ni awọn gbe igbesẹ naa lati bu ọla fun ẹni ti ọla tọ si, ati lati sami ẹyẹ fun ipapoda agba oṣelu naa.
Abilekọ Tinubu-Ojo rọ gbogbo awọn babalọja ati iyalọja atawọn igbimọ alakooso awọn ọja kaakiri origun mẹrẹẹrin ipinlẹ Eko lati ri i pe wọn tẹle aṣẹ yii, ki wọn ma ṣe silẹkun ọja fun ẹnikẹni, lati fi kẹdun fun Baba Jakande.
“Gbogbo wa la mọ pe gomina ana nipinlẹ Eko yii lo asiko ati iṣejọba rẹ lati tun ilu Eko ṣe, ko si pọ ju ta a ba ya ọjọ kan sọtọ fun iru eeyan bẹẹ, ohun to daa ni. Mo rọ gbogbo ẹyin adari ati alakooso ọja lati tẹle aṣẹ yii.” Bẹẹ ni iyalọja agba naa sọ.
Tẹ o ba gbagbe, Ọjọbọ, ọjọ kọkanla, oṣu keji, ọdun yii, ni Lateef Jakande, to jẹ gomina akọkọ fun ipinlẹ Eko labẹ ijọba oloṣelu jade laye lẹni ọdun mọkanlelaaadọrun-un, ti wọn si sin oku rẹ tiyi-tẹyẹ lọjọ keji, ọjọ Ẹti, Furaidee, si itẹkuu kan to wa lagbegbe Ikoyi.
Ọpọ ibanikẹdun, iranti rere ati idaro lo ti n rọjo latigba ti baba naa ti doloogbe.
Awọn ọmọ, ọmọọmọ ati iyawo lo gbẹyin baba yii