Tori Ọlọrun, ẹ wo ti aawẹ Ramaddan, ẹ mu adinku ba ọwọngogo ounjẹ yii – Sultan

Gbenga Amos

Olori ẹsin Musulumi, Sultan tilu Sokoto, ti parọwa sijọba lati wa nnkan ṣe ni yajoyajo, ki adinku le ba ọwọngogo ounjẹ to gbode kan lasiko yii, paapaa nitori awọn Musulumi to fẹẹ bẹrẹ aawẹ ọdọọdun wọn laipẹ sasiko yii.

Nibi eto idije kewu kike kan to waye lopin ọsẹ yii, niluu Bauchi, ni Sultan ti rawọ ẹbẹ yii, gẹgẹ bii alejo pataki nibi ayẹyẹ naa.

Sultan ni ojuṣe ijọba ni lati ṣiṣẹ papọ, ki ounjẹ rẹpẹtẹ le wa faraalu, ki wọn si ri i ra lowo ti ko gara.

O tun rawọ ẹbẹ sawọn ọlọja lati ṣaanu araalu, ki wọn ma ṣe maa gbowo leri ọja, paapaa lasiko aawẹ Ramaddan, tori o ti fẹẹ di aṣa wọn lati sọ owo ọja di ilọpo ilọpo lasiko aawẹ awọn ẹlẹsin Musulumi naa.

Sultan ni: “Mo ro pe ohun to kan fẹyin onṣejọba ni pe kẹ ẹ fori kori, kẹ ẹ ṣiṣẹ papọ, lati mọ bi adinku ṣe fẹẹ ba ounjẹ to wọn gegere lasiko yii, inira yii ti pọ ju faraalu, ẹ mu owo ounjẹ walẹ, ki gbogbo wa le gbadun oṣu aawẹ Ramaddan wa.

“Emi o ro pe iyẹn pọ ju fun wa lati beere lọwọ ijọba, ṣebi awa la dibo yan wọn sipo lati sin wa, ki i ṣe ki wọn sọ wa di ẹru ti yoo maa sin wọn.

“Mo tun n lo anfaani yii lati bẹ ẹyin ọlọja, ẹyin olounjẹ ati ẹyin oniṣowo gbogbo, ẹ bẹru Ọlọrun Ọba o, ẹ fibẹru Ọlọrun kun ọja tẹ ẹ n ta o, kẹ ẹ ranti pe Ọlọrun maa bi yin leere ọrọ lọjọ idajọ tẹ ẹ ba dewaju ẹ. Dipo tẹ ẹ fi maa gbowo leri ọja tabi jẹ ere ajẹpajude, niṣe ni kẹ ẹ dinwo ọja ku, kẹ ẹ le ri ojuure ati iyọnu Ọlọrun Ọba.

Sultan tun gba awọn oloṣelu lamọran pe ki wọn ma ṣe sọ ọrọ idibo di ọranyan, tori Ọlọrun ti mọ ẹni to maa wọle ati ẹni to maa fidi rẹmi, ibaa jẹ nipinlẹ tabi tijọba apapọ.

 

Leave a Reply