Tori awọn ọmọ mi ni mo ṣe fiṣẹ olowo nla silẹ ni Naijiria, ti mo n ṣe lebura niluu oyinbo- Ṣọla Ṣobọwale

Faith Adebọla

 Ọkan ninu awọn irawọ oṣere-binrin onitiata nilẹ wa nni, Ṣọla Ṣobọwale. Awọn ololufẹ rẹ pọ gan-an, ti wọn n gbadun bi mama naa ṣe jafafa, to si n fara ṣiṣẹ ninu awọn fiimu to ti kopa. Ṣugbọn lati bii ọdun diẹ sẹyin ni wọn ko ti ri agba-ọjẹ yii ninu fiimu tabi sinima mọ, ọpọ lo si n ṣe ni kayeefi ohun to mu ki Ṣọla Ṣobọwale di ‘ẹ kuu atijọ’ lagbo tiata lasiko yii.

Ṣọla ti ṣalaye pe ọrọ ọmọ loun ṣe lọ o, o ni tori koun le tọ awọn ọmọ t’Ọlọrun fi jinki oun yanju, ki wọn kawe doju ami, ki wọn si ri ẹni foju jọ lo mu koun jokoo ti wọn lẹyin odi. O tun dẹbi ru ijọba Naijiria fun eto ẹkọ to polukurumuṣu labẹle wa, o ni eto ẹkọ tiwa to sọ ẹkọ to yẹ ki ọmọ ka fọdun mẹta tabi mẹrin di ọlọdun mẹfa si mẹjọ lo jẹ koun yaa palẹ awọn ọmọ oun mọ, toun fi ko wọn lọọ kawe ni aburọọdu.

Ninu ifọrọwanilẹnu wo kan to ṣe pẹlu oniroyin ayelura nni, Chude Jideonwo, niṣe lomije n da loju obinrin naa bo ṣe ranti ipinnu rẹ lati fi iṣẹ to n mowo gidi wọle fun ni Naijiria silẹ, toun waa lọ di ẹni to n ṣe abọọṣẹ niluu eebo, koun le raaye mojuto awọn ọmọ oun. Bo ṣe n fi ankaṣifi nuju rẹ, bẹẹ lo n gba awọn abiyamọ ati obi lamọran. Eyi ni diẹ ninu ọrọ to sọ:

“O nidii pataki ti mo ṣe fi Naijiria silẹ. O ga o, ṣugbọn mo dupẹ lọwọ Ọlọrun. Ọmọ, ki i ṣe keeyan kan bimọ lasan ni. Niwọn igba teeyan ba ti pinnu lọkan ẹ pe oun fẹẹ bimọ, tọhun gbọdọ san ṣokoto ẹ lati gbe bukaata awọn ọmọ naa. Ododo ẹyẹ lọmọ, eeyan o gbọdọ bi wọn lati fi wọn laalaṣi laye, O ko si gbọdọ bi wọn tori kẹlomi-in le ba ẹ tọ wọ. Iwọ lo bi wọn, iwọ gan-an funra ẹ lo ni ojuṣe lati duro ti wọn, lati tọ wọn. Mo bi awọn ọmọ mi. Baba mi, ọga ileewe to ti fẹyinti, iya mi, ọga ileewe to fẹyinti loun naa, k’Ọlọrun ba mi fọrun kẹ wọn, mo mọ ohun ti wọn ṣe fun mi ati fawọn ọmọ to ku. Mo mọyi keeyan ran ọmọ niwee, ogun pataki, nnkan aritọkasi kan ṣoṣo teeyan le fi le ọmọ lọwọ niyẹn. Ọkọ ti mo fẹ, ọga to n gbaayan siṣẹ ni, iyẹn jẹ ki n ri bi wọn ṣe maa n yẹ iwe awọn ti wọn n waṣe wo, ti wọn maa yọ ti awọn to lọ si poli, awọn to lọ si fasiti, ati awọn to kawe niluu oyinbo sọtọọtọ. Atigba yẹn ni mo ti pinnu pe, ni temi o, awọn ọmọ ti mo bi, fasiti ni wọn maa lọ, ninu ki wọn lọ si Fasiti Ibadan (UI), tabi ti Ifẹ (OAU) tabi Fasiti Eko (UNILAG).

Ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe oni iwọde, ọla iyanṣelodi, ọtunla, wọn daṣẹ silẹ, ẹkọ to yẹ ki wọn fọdun mẹta ka n di ọdun mẹfa mọ wọn lọwọ, ni mo ba fi pinnu pe ki wọn lọọ kawe niluu oyinbo, idi ti mo fi ko awọn ọmọ mi lọ London, lorileede United Kingdom, niyẹn.

“Mo ko wọn lọ si England, mo fi wọn sileewe, mo pada wa si Naijiria ni temi, mo n ṣamojuto wọn, mo n ṣọ wọ. Lẹyin oṣu kan, mo pada lọọ wo wọn lọhun-un, mo ri i pe wọn ti bẹrẹ si i yatọ si ọmọ ti mo ko wa, mo ri apẹẹrẹ pe iya wọn o si larọọwọto wọn ti n mu ki wọn yatọ, mo ni: ‘Aaa, Isirẹli, mo de lati wọnu agọ rẹ o’. Ẹ gbagbe nipa gbajumọ, ẹ fi ọrọ okiki silẹ. Tori ẹ ni mo ṣe kuro ni Naijiria, ki n le ran wọn lọwọ kawọn naa le jẹ eeyan nigbesi aye wọn.

“Mo dẹ dupẹ lọwọ Ọlọrun o, wọn ti ṣaṣeyọri lonii, gbogbo wọn ni wọn ti n ṣiṣẹ owo, ti wọn n sọ fun mi pe: “Mọmi, ẹ ṣeun fun bẹ ẹ ṣe fara yin rubọ fun wa titi doni, o ya, ẹ waa maa lọ, ẹ pada sẹnu iṣẹ tẹ ẹ n ṣe to ti mọ yin lara.”

Oludọtun Ṣobọwale lorukọ ọkọ ti Ṣọla fẹ lọpọ ọdun sẹyin, bo tilẹ jẹ pe igbeyawo naa ti fori ṣanpọn tipẹ. Ọmọ marun-un si ni Ọlọrun fi ta wọn lọrẹ.

Leave a Reply