Faith Adebọla, Eko
Ọwọ agbofinro ti tẹ afurasi ọdaran kan, Cletus Wilson, l’Ọjọbọ, Tọsidee ọsẹ yii, latari bi wọn ṣe loun lo pa ekeji ẹ, John Okoro, ti wọn jọ n ṣiṣẹ, wọn lo fẹẹ fi ẹya ara ẹ ṣoogun owo ni.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ileewe Poli ipinlẹ Eko (Lagos State Polytechnic), ni lawọn mejeeji ti n ṣiṣẹ sikiọriti, ninu ọgba ileewe naa to wa loju ọna marosẹ Ikorodu si Ṣagamu, nipinlẹ Eko.
Wọn ni ẹka ti wọn ti n kẹkọọ nipa imọ kọmputa nileewe naa ni wọn yan afurasi ọdaran yii si lati maa ṣọ, ibẹ lo maa n wa lojoojumọ, igbo ṣuuru kan si wa lẹyin yara ikawe ẹka yii.
Inu igbo ṣuuru yii ni wọn ni Cletus tan ẹlẹgbẹ rẹ, John, to ti doloogbe bayii lọ. Ọlọrun lo mọ irọ to pa fun un tiyẹn fi tẹle e.
Iwadii tawọn ọlọpaa ṣe fihan pe irin nla kan lafurasi ọdaran yii la mọ oloogbe naa lori lojiji tiyẹn fi ṣubu lulẹ, ni Cletus ba yọ ọbẹ ti i, o dumbu ẹ bii ẹran, ẹyin naa lo bẹrẹ si i kun ẹya ara rẹ, wọn lo ti ge ọwọ oloogbe naa sọtọ, o tun ge awọn ẹya ara rẹ mi-in, o di wọn sinu apo kan.
Wọn lọkunrin yii ti fẹẹ maa gba ọna ẹyin sa lọ kawọn sikiọriti ti wọn jọ n ṣiṣẹ too fura si i, ti wọn si ni ko jẹ kawọn wo ẹru to di sinu apọ to gbe dani, laṣiiri ba tu.
Wọn fọrọ yii to awọn ọlọpaa leti ni teṣan wọn to wa n’Ikorodu, ni wọn ba waa fi pampẹ ofin gbe afurasi apaayan yii.
DPO ọlọpaa to wa ni tẹsan ọhun, Ọgbẹni Adekunle Omiṣakin, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fun Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN). O lawọn ti fi Cletus ṣọwọ si ẹka ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, fun iwadii si i, ki wọn le mọ igbeṣẹ to kan lori ọrọ ọhun.