‘Tori pe a ko rẹni ya wa lowo lati ṣowo to wu wa la fi bẹrẹ si i digunjale’

Faith Adebọla, Eko

Awọn adigunjale meji yii, Sule Abdulkareem, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, pẹlu ekeji ẹ, Celestine Joseph, ni nitori owo tawọn fẹẹ bi bẹrẹ okoowo tawọn wa titi ti ko sẹni to ya awọn lo mu kawọn maa digunjale, wọn lowo ọhun lawọn n dọgbọn tu jọ diẹdiẹ.

Ọsan ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii lọwọ ikọ ọlọpaa to n gbogun ti idigunjale, SARS, tẹ awọn ọkunrin meji ọhun lagbegbe Anthony Village, l’Ekoo.

Alaye ti wọn ni Abdulkareem ṣe fawọn agbofinro ni pe ileeṣẹ to n taja lori ikanni, Jumia, loun ti mọ ekeji oun, Joseph, o lawọn jọ n wa ọkada (Dispatch Rider) fun ileeṣẹ naa ni. O ni ọrẹ oun yii lo fẹẹ bẹrẹ okoowo ile ọti, o fẹẹ ṣi rẹsitọranti, o si nilo miliọnu kan aabọ Naira lati fi bẹrẹ.

O loun pẹlu rẹ lawọn jọ daamu wa owo naa kaakiri, ṣugbọn kọbọ lo kere ju, ẹni kan ko ya awọn, kawọn too pade ọkunrin kan to sọ fawọn pe awọn le ri owo naa ya ti awọn ba ti ni ohun ti awọn le fi duro.

Motọ tawọn maa fi ṣe oniduuro yii lo lawọn n wa tawọn fi ronu idigunjale, igba to si jẹ pe awọn ọkọ to ṣi dun-un wo lo n ba UBER ṣiṣẹ, eyi lo mu kawọn ke si awakọ ọhun lori foonu pe ko gbe awọn lọ si ọna Anthony. Toyota Corolla to gbẹ kan lawakọ naa gbe wa.

O ni bo ṣe ku diẹ kawọn de agbegbe Anthony lawọn ti fẹẹ ja awakọ naa lole, ṣugbọn boya o fura ni o, niṣe lo n tẹna ọkọ faa-faa-faa, lawọn ba fi i silẹ pe boya awọn maa ri ibomi-in to parorọ tawọn ti maa le ja mọto naa gba lọwọ ẹ, lo fi di pe ọwọ ọlọpaa SARS lawọn waa ko si yii.

Nigba ti wọn bi wọn leere ibi ti wọn ti ri ibọn ti wọn n lo, Joseph  ni ọrẹ awọn kan lo fun awọn nigba kan, onitọhun ko si si l’Ekoo mọ. O ni ibọn naa ti wa lọwọ awọn tipẹ, awọn maa n lo o lati daabo bo ara awọn lọwọ awọn janduku Apapa tawọn n gbe ni.

Ṣa, awọn afurasi mejeeji yii ti balẹ si ahamọ awọn ọtẹlẹmutẹ ni Panti, Yaba.

Leave a Reply