Tori pe wọn yinbọn paayan meji, afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun meje dero ahamọ l’Abẹokuta

Gbenga Amos, Abẹokuta
Lati ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un yii, lawọn gende mẹrin tẹ ẹ n wo yii ko ti le sun oorun asunwọra lori bẹẹdi kaluku wọn bii ti tẹlẹ mọ, ahamọ awọn ọlọpaa ni wọn n sun, ti wọn n ji, afaimọ ni ko si ni i jẹ ibẹ ni wọn maa gba dele-ẹjọ latari ẹsun pe wọn n ṣe ẹgbẹ okunkun, awọn ni wọn si wa nidii bi wọn ṣe yinbọn pa eeyan meji lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtalelogun, oṣu yii, nigboro Abẹokuta.
Ọtọ lorukọ tawọn obi sọ awọn mejeeje, ọtọ lorukọ inagijẹ ti wọn sọ ara wọn, gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe sọ. Orukọ awọn afurasi naa ni Kazeem Ogundairo, ti inagijẹ rẹ n jẹ NẸPA, Idris Nasiru, ti wọn n pe ni Aloma, Ayọ Joshua, ti wọn n pe ni Terry G, ati Damilare Shogbamu, Dhray ni wọn mọ oun si.
Awọn mẹta to ku ni Bisiriyu Ibrahim Owoyele, Jamiu Labulọ ti inagijẹ rẹ n jẹ Jay Boy, ati Taiwo Ọlaitan.
Oyeyẹmi ni ipe pajawiri tawọn aladuugbo kan fi ṣọwọ sileeṣẹ ọlọpaa latari bawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ṣe n da ilu ru, ti wọn ko awọn araalu lọkan soke, paapaa lagbegbe Ijaye si Iyana Mọṣuari, lọjọ Tusidee ọhun, lo mu kawọn agbofinro sare debẹ, ṣugbọn aya ko awọn ẹlẹgbẹkẹgbẹ ọhun, niṣe ni wọn doju ija kọ awọn ọlọpaa, ti wọn fija pẹẹta pẹlu wọn pẹlu awọn nnkan ija oloro ti wọn ko dani, awọn kan lara wọn si sa lọ.
Ṣe bi ekute ba yari, ologbo aa fẹsọ mu un ni, awọn ọlọpaa ti ASP Bọlanle Muritala ko sodi, ati ẹṣọ DSS gba agbara lọwọ awọn elewu ẹda yii, ibẹ lọwọ ti ba meje lara wọn.
Ṣaaju, lawọn afurasi ẹlẹgbẹ okunkun yii ti yinbọn pa gende meji kan ni ikorita Ijaye naa, lẹgbẹẹ ileepo kan to wa nibẹ. Wọn ni afurasi ẹlẹgbẹ okunkun lawọn mejeeji ti wọn da ẹmi wọn legbodo ọhun.
Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ pe niṣe lawọn mejeeji to doloogbe naa duro sẹgbẹẹ ara wọn, o si jọ pe awọn to pa wọn yii wa ninu ẹgbẹ okunkun mi-in ni, ọkọ ayọkẹlẹ kan ni wọn gbe wa, wọn wa mọto naa kọja niwaju awọn mejeeji, ki wọn too yipada biri, wọn gba ọna ti ko yẹ ki wọn gba, kẹnikẹni si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, iro ibọn ti dun lau, lau, wọn ti mu awọn mejeeji balẹ, ni wọn ba sa lọ.
Laaarọ ọjọ Iṣẹgun naa ni awọn afurasi ẹlẹgbẹ okunkun ti wọn pa ọmọ ẹgbẹ wọn yii rọ da soju popo, wọn bẹrẹ si i fọ igo, wọn n ju igi, wọn lawọn n fẹhonu han lori iku ẹni wọn, wọn si da omi alaafia agbegbe naa ru kawọn ọlọpaa too kapa wọn.
A gbọ pe wọn ti sinku awọn mejeeji to doloogbe naa, wọn lawọn obi ati mọlẹbi wọn lọọ sinku wọn.
Ẹnikan to ba ALAROYE sọrọ, ṣugbọn ti ko fẹ ka darukọ oun, sọ pe oun mọ baba ọkan ninu awọn ọmọ ti wọn yinbọn fun naa, o lawọn jọ n gbe adugbo ni, ọmọ ilu kan naa lawọn, o si ti pẹ ti ọmọ rẹ ti n huwa ipanle, ṣugbọn niṣe ni baba rẹ maa n pọn sẹyin rẹ lọpọ igba.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti paṣẹ pe ki iwadii to lọọrin waye lori iṣẹlẹ yii, ki wọn si tọpa awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yooku, ki gbogbo wọn le fimu kata ofin lori ẹgbẹ to lodi sofin ti wọn n ṣe.

Leave a Reply