Tori wahala Hijaabu, ijọba Kwara fi tipa ṣilẹkun ileewe ti wọn ti pa

Faith Adebọla

Tipa tikuuku nijọba Kwara sọ ọrọ da lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, pẹlu bi wọn ṣe yan igbimọ amuṣẹya kan lati ri i pe awọn ileewe ti wọn yari pe awọn o ni i ṣilẹkun fawọn akẹkọọ to wọ ibori Musulumi ti wọn n pe ni biHijaabu, ṣilẹkun naa lọran-anyan.

Ọjọruu, Wẹsidee to kọja yii, nijọba ni kawọn ileewe mẹwaa tọrọ naa kan bẹrẹ iṣẹ pada ni kia, ki wọn si faaye gba awọn akẹkọọ ẹlẹsin Musulumi  lati wọ hijaabu wọn, bi wọn ṣe fẹ.

Ṣugbọn ọpọ awọn ileewe naa lo ṣi wa ni titi pa bo tilẹ jẹ pe awọn akẹkọọ kan ati awọn olukọ duro siwaju geeti awọn ileewe naa, ti kaluku wọn n  sọrọ nipa iṣẹlẹ ọhun.

Akọwe iroyin fun lẹka eto ẹkọ nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Yakub Ali-Agan sọ pe ijọba ti yan igbimọ amuṣẹya kan lori ọrọ yii, igbimọ naa si ti n lọ kaakiri lati ri i pe gbogbo ileewe pa aṣẹ tijọba pa mọ. O ni ajọ to n ri si  ọrọ ẹkọ nipinlẹ Kwara, Kwara State Teaching Service Commission (KWATESCOM) ti paṣẹ fawọn tiṣa lawọn ileewe mẹwaa tọrọ kan tawọn ẹlẹsin Kristẹni da silẹ (mission schools) lati pada sẹnu iṣẹ lọjọ Ẹti,  Furaidee.

Yakub ni titi pa lawọn ileewe kan wa titi di igba ti igbimọ amuṣẹya naa yọ si wọn, ti wọn si ṣi geeti naa fawọn olukọ ati akẹkọọ lati wọle. “Ni kọlẹẹji Cherubim and Seraphim to wa ni Sabo Oke, n’Ilọrin, niṣe lawọn alufaa ṣọọṣi atawọn alakooso ṣọọṣi naa ti geeti ileewe pa, ti wọn si ko nnkan di ẹnu ọna lati ma jẹ kẹnikẹni wọle, afigba tawọn igbimọ  amuṣẹya yii de’bẹ pẹlu awọn agbofinro.

“Bakan naa lọrọ ri nileewe Baptist LGEA Primary and Secondary Schools, Surulere, Ilọrin, wọn ni gbogbo nnkan ti n lọ ni mẹlọ-mẹlọ kawọn igbimọ amuṣẹya naa too kuro nibẹ.”

Amọ ṣa, ninu fidio kan ti wọn n pin kiri lori atẹ ayelujara, wọn yaworan bi wọn ṣe tilẹkun geeti ileewe Cherubim and Seraphim, Sabo-Oke pa, ti wọn si ja iyanrin ati okuta lati di geeti naa pa kẹnikẹni ma le wọle. Iwaju ita lawọn akẹkọ ati olukọ duro si, bawọn kan ṣe wọ hijaabu ninu awọn akẹkọọ naa lawọn kan wọ aṣọ ṣọọṣi (Sutana) wọn wa, ko si si olukọ to  ṣetan lati kọ awọn akẹkọọ naa. Wọn tun ta akọle gadagba meji mọ geeti  naa nibi ti won kọ ọ si pe “A ko fẹ Hijaabu nileewe wa o” ati awọn ọrọ  ẹhonu mi-in.

Ọrọ naa ko yatọ nileewe Bishop Smith Memorial College to wa ni ọna Agba Dam, ati ti Saint James Secondary School, Taiwo Isalẹ, ko si eto ẹkọ kan to waye nibẹ, niṣe lawọn olukọ n parojọ siwaju geeti, ti wọn n  sọrọ iṣẹlẹ naa laarin ara wọn, bo tilẹ jẹ pe geeti ileewe wa ni ṣiṣi.

Leave a Reply