Tori wọn ṣẹ sofin Korona, ile-ẹjọ ni ki Naira Marley sanwo itanran

Faith Adebọla

Owo itanran ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un meji naira (N200,000) nile-ẹjọ to n gbọ awọn ẹsun akanṣe nipinlẹ Eko paṣẹ pe ki gbajugbaja olorin taka-sufee nni, Azeez Adeshina Fashọla, ti inagijẹ rẹ n jẹ Naira Marley ati maneja ẹ, Seyi Awonuga, lọọ san sapo ijọba latari bi wọn ṣe jẹbi rirufin arun Korona.

Nnkan bii aago mẹrin ọsan Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu yii, nigbẹjọ naa waye n’Ikẹja, nigba tawọn mejeeji n kawọ pọnyin rojọ ni kootu ọhun. Ẹsun kan ṣoṣo ti wọn ka si wọn lẹsẹ ni pe wọn rinrinajo lati Eko lọ si Abuja lọjọ kẹtala, oṣu kẹfa, ọdun yii, eyi to lodi si aṣẹ tijọba pa nigba naa pe ki onile gbele ẹ, nitori arun Korona to gbode.

Wọn ni iwa to hu naa tako isọri kẹrin, apa kẹsan-an, ofin nipa eto ilera araalu ti ijọba ipinlẹ Eko n lo, ati aṣẹ ti Aarẹ ilẹ wa pa pe ko ma ṣe si lilọ bibọ lati ipinlẹ kan si omi-in lasiko ọhun.

Ṣe tẹlẹjọ ba ti mọ ẹjọ ẹ lẹbi, ki i tun pẹ lori ikunlẹ, lọwọ kan ti wọn ti ka awọn ẹsun naa si wọn leti lawọn mejeeji ti sọ pe awọn jẹbi, ti wọn si tọrọ aforiji, ni Adajọ A. Taiwo ba paṣẹ pe ki awọn mejeeji san owo itanran

Leave a Reply