Tori wọn n jẹun lasiko aawẹ, ọlọpaa Sharia rọ awọn mọkanla da satimọle ni Kano

Faith Adebọla

Kaakiri awọn agbegbe yipo ilu Kano, lapa Oke-Ọya, lawọn ọlọpaa Sharia ti fi pampẹ ofin gbe awọn eeyan mọkanla kan l’Ọjọbọ, Tọsidee yii. Ẹṣẹ ti wọn ṣẹ ni pe wọn ka wọn mọ’bi ti wọn ti n jẹun lọsan-an aawẹ, lasiko tawọn ẹlẹgbẹ wọn ẹlẹsin Musulumi n pa ebi mọnu lọwọ.

Ọga agba ẹṣọ agbofinro Hisbah, ti wọn tun n pe ni ọlọpaa Sharia, Dokita Aliyu Musa Kibiya, sọ pe loootọ lawọn mu awọn afurasi ọdaran naa nibi ti wọn ti n jẹun lọsan-an gangan, o ni obinrin mẹjọ, ọkunrin mẹta, lo ti wa lahaamọ awọn tori ẹṣẹ ọhun.

Aliyu ni aawẹ gbigba fawọn Musulumi labẹ ofin Sharia, ọran-anyan ni, ‘nọmba tulaasi’ ni, ki i ṣe ‘nọmba t fẹ bẹẹ’, paapaa tonitọhun ko ba ti ni iṣoro aisan tabi ailera to lagbara.

“A maa ṣewadii nipa awọn tọwọ ba wọnyi, boya wọn ni idi to bofin mu ti ko fi yẹ ki wọn gbaawẹ to n lọ lọwọ yii, ti wọn ba nidii to tẹwọn, a maa fi wọn silẹ, ṣugbọn ti ko ba si alaye to mọyan lori, a maa la wọn lọyẹ, tabi ka ba wọn ṣẹjọ.

“Ni ti awọn obinrin, ọrọ tiwọn lagbara, tori boya wọn gbaawẹ tabi wọn o gbaawẹ o, ko yẹ ki wọn maa jẹun ni gbangba rara lasiko aawẹ. Ẹnikẹni ta a ba ri to ṣe bẹẹ, a maa fi pampẹ ofin mu un.

Aawẹ gbigba ninu oṣu Ramadaani pọn dandan fun Musulumi to ba ti kuro lọmọde, to si ni ilera, ayafi awọn ti wọn ba n rin irinajo, awọn obinrin ti wọn n ṣe nnkan oṣu lọwọ, ati awọn arugbo tagbara wọn o gbe e.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, oriṣiiriṣii awuyewuye lo ti n lọ laarin awọn araalu pẹlu bawọn ẹṣọ alaabo Hisbah yii ṣe n lo ida ofin wọn bo ṣe wu wọn, ti eyi si n kọ awọn eeyan lominu.

Leave a Reply