Nitori ‘Yoruba Nation’, iwọde nla yoo waye lọdọ ajọ Iṣọkan Agbaye l’Amẹrika

Faith Adebọla

Bi ko ba si ayipada, miliọnu kan tabi ju bẹẹ lọ awọn ọmọ orileede yii lati apa Guusu Naijiria to wa niluu oyinbo ni yoo kopa ninu ipolongo ati iwọde wọọrọwọ nla kan to maa waye ni olu-ilu ajọ Iṣọkan Agbaye, iyẹn United Nations (UN), lorileede Amẹrika, loṣu kẹsan-an, ọdun yii, lati ṣatilẹyin fun idasilẹ Orileede Oodua, ti wọn n pe ni Yoruba Nation. Ọjọgbọn Banji Akintoye, olori ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua atawọn eeyan nla nla mi-in ti wọn n ṣoju awọn ẹya mi-in naa ti wọn nifẹẹ si idasilẹ orileede wọn lati ilẹ Ibo, Middle Belt, wa lara awọn to maa ṣaaju iwọde naa.

Ba a ṣe gbọ, ọsẹ kan gbako, ọjọ kẹrinla si ikọkanlelogun, oṣu kẹsan-an ni ipolongo naa yoo waye, ti wọn yoo maa yan bii ologun yipo olu-ile ẹgbẹ UN, lati pe akiyesi awọn alaṣẹ agbaye si ibeere wọn lori wiwọgi le ofin ọdun 1999 tijọba Naijiria n lo, ki wọn si faaye gba ẹya Yoruba atawọn ẹya to ba fẹẹ ya kuro lara Naijiria pe ki wọn bẹrẹ igbesẹ idaduro wọn.

Ọsẹ ti wọn fi igboke-gbodo yii si ṣe kongẹ pẹlu apero agbaye kẹrindinlọgọrin ti ajọ UN ọhun, asiko naa lawọn alakooso orileede kari aye yoo pesẹ sipade wọn, ireti si wa pe Aarẹ ilẹ wa, Mohammadu Buhari, ati ikọ rẹ yoo wa nipade ọhun.

A gbọ pe ipolongo ti wọn fẹẹ ṣe yii, ki i ṣe fun awọn ti wọn n wa Yoruba Nation nikan, awọn ẹya mi-in, yatọ si Yoruba naa wa lara awọn to n ṣagbatẹru eto yii, labẹ ẹgbẹ kan to wa fun ikojọpọ awọn ẹya to fẹẹ da duro ni Naijiria, Nigerian Indigenious Nationalities Alliance for Self-Determination (NINAS.)

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun Ọjọgbọn Akintoye, Ọgbẹni Maxwell Adelẹyẹ, fi lede, o ni awọn agbaagba Isalẹ-Ọya, iyẹn ẹkun Guusu (South) ati Aarin-Gbungbun (Middle-Belt) ilẹ Naijiria wa lara awọn to maa kopa nibi ipolongo ọhun.

Lara wọn ni Akọwe-agba fun ẹgbẹ NINAS, Ọjọgbọn Yusuf Turaki, Kọmiṣanna feto ẹkọ nipinlẹ Ọṣun tẹlẹ ri, Amofin Tony Nnadi, ati Alaga apapọ fun ẹgbẹ Ilana ọmọ Oodua, Ọjọgbọn Wale Adeniran.

Banji Akintoye ni: “A ti n gbọ ahesọ kan pe awọn kan ko ara wọn jọ, wọn tẹ atẹjade lati gbegi dina ipolongo ta a fẹẹ ṣe yii, wọn ni kijọba fofin de wa, ka ma le lọ siwaju ajọ Iṣọkan Agbaye nibi apero wọn.

Ẹ jẹ ko ye yin pe a oo lọọ dara pọ mọ apero UN, ipolongo ati yiyan bii ologun la fẹẹ ṣe, a fẹ kawọn alaṣẹ agbaye to maa pesẹ mọ erongba ati ipinnu wa ni. Ohun akọkọ ta a fẹẹ beere ni pe ki wọn wọgi le ofin ọdun 1999 ti a n lo yii, a ti fi ẹri to pọ to han pe jibiti ni, ẹtan ni, niṣe ni wọn fi ofin naa yan awọn eeyan Guusu ati Aarin-Gungbun jẹ.

Gbogbo awọn ọmọ Guusu ati Aarin-Gungbun to wa l’Amẹrika ati kaakiri agbaye la ke si, gbogbo wọn la reti nibi eto ti miliọnu kan eeyan ti fẹẹ yan bii ologun yii.” Akintoye lo sọ bẹẹ

Leave a Reply